MO SE TAN LATI JE KAWON ARAALU JE MUDUNMUDUN IJOBA AWAARAWA - SEGUN SOWUNMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 23, 2018

MO SE TAN LATI JE KAWON ARAALU JE MUDUNMUDUN IJOBA AWAARAWA - SEGUN SOWUNMI

Agbenuso fun adije sipo Aare orileede Naijiria lodun 2019 labe asia egbe oselu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, Ogbeni Segun Showunmi to fe e jade dupo asoju-sofin nile igbimo asofin (House of Rep) niluu Abuja ti seleri pe bawon toun fe e loo soju ba fi le gbe oun wole, oun se tan lati rii daju pe won je mudun-mudun ijoba awaarawa.


Segun Showunmi to fe e jade lati ekun Abeokuta South Federal Constituency soro yi lasiko to loo sabewo sawon agbaagba atawon oloye egbe oselu naa ni woodu e lojo Satide to koja yi, iyen ana.

O ni bi won ba foun lanfaani lati loo soju won niluu Abuja lodun 2019, ati pe bo se je pe ife toun ni si won lo je koun fe e loo soju won, idi ni yii toun yoo je gbiyanju gbogbo agbara oun lati rii pe awon eto to to si won to won lowo.

O tun so pe boun ba koko de be, nnkan akoko toun yoo se ni lati wa ona bi won yoo se maa gbe igbe aye irorun, tawon odo yoo maa ri owo lojoojumo.

Bakan lo tun je ko di mi mo pe imo ero igbalode, iyen ICT ko nii je nnkan ti yoo soro fun won lati je anfaani e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI