OMIYALE: KABIYESI SUNKUN NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 23, 2018

OMIYALE: KABIYESI SUNKUN NITA GBANGBA

A fi ki ijoba ipinle Jigawa, paapaa ijoba apapo tete wa nnkan se si oro omiyale to sele lojo Fraide si Satide to koja yi, pelu bo se gba opolopo dukia je, to si tun fopo emi sofo danu.


Eyi gan an la gbo pe o fa a ti Oba Sarkin Auyon Hadejia, Alaaji Umar Baffa fi bere sii sunkun nita gbangba, nigba to n rawo ebe sijoba apapo pe ki won tete boju aanu wo awon nipinle naa, paapaa ladugbo ti omiyale naa ti sele.

AWIKONKO gbo pe ojo kan to ro, lo mu ki odo Jadeja-Jamaare kun, to si yabo ilu, nibi to ti loo fi dukia ti ko din ni bilionu mewa sofo danu.

Baffa nigba to n soro so pe awon eeyan oun meta pelu awon to padanu emi won, ti dukia won ti ko din in ni bilionu meta ataabo (3.5) naira si ba omiyale naa lo.

O ni fun bi ojo meji ti ojo arooroda naa fi ro, ko seni to le jade, ko si si nnkan tawon le se lati da omiyale naa duro.

Lara awon abule to ba isele naa lo ni Jura, Rafeji, Uza, Gamakwai, Zabaro, Ayama atawon min in ta a ko le daruko won tan.

Baffa tun so pe nigba tisele naa bere, se lawon eeyan bere sii poora, tawon ko mo ibi ti omi naa gbe won lo, igba to da die lo so pe awon se e bere sii ri oku won kaakiri ilu.

Bakan naa lo je ko di mi mo pe odun 2001 niru isele bayii ti waye gbeyin, to si n be ijoba apapo pe ko fi ipinle Jigawa kun awon ipinle mokanla ti won seto lati ran lowo lori isele omiyale naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI