SOJA MU OTI YO TAN, LO BA PA OGA E DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 24, 2018

SOJA MU OTI YO TAN, LO BA PA OGA E DANU

SERUBAWON AYEGBAJEJE

Kayeefi loro soja kan ta a ko tii moruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan lori bi won se loo muti yo tan, to si fi ibon pa oga e danu lopin ose to koja yi.


Baraaki Magadisu, iyen (Magadisu Cantonment) la gbo pe isele naa ti sele.

Ohun ta a gbo ni pe won fun soja naa ni aaye lati loo sinmi fun iseju die kuro lenu ise, ko si tun ri aaye lati jeun. Sugbon nigba to maa lo, ile oti la gbo pe soja naa ti won ni ipo e ko tii ju 11NA lo gba lo.


Won ni se lo mu oti yo bamubamu lai ranti pe enu ise loun wa. Nigba to si maa pada de enu ise e pada, isokuso ni won lo n ba oga e to fun laye so, tiyen si pase fun un pe ko loo paaro aso e si aso ise.

AWIKONKO gbo pe nigba to maa paaro aso e tan, to si jade sita pelu ibon e lowo, se lo gbe ibon naa, to si yin in fun oga e, ti won ni 99NA loun lori, tiyen si ku lesekese.


Ko tan sibe rara, won ni bo se rii pe oun ti yinbon pa oga oun, to si see se ko je akoba nla foun, loun naa ba gbiyanju lati yinbon pa ara e.

Won ni bo se gbe ibon naa sori, in fun ara e, se ni owo e tase to si je pe enu e nibon naa fo danu.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI