NITORI ESUN KOKEENI: OWO OLOPAA TE AMEACHI ATAWON ORE E LORILEEDE MALAWI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 15, 2018

NITORI ESUN KOKEENI: OWO OLOPAA TE AMEACHI ATAWON ORE E LORILEEDE MALAWI

"E se wa jeje, ise esu ni" loro ebe to n tenu awon omo Naijiria meta kan ti won fi orileede Malawi sebugbe, awon ti won ni won ko nise meji ti won n se ju kokeeni tita lo. Lai pe yi lowo palaba won segi.


Nze Chidiebere, omodun metadinlogbon (27); Collins Okoligwe Amaechi, omo ogbon odun (30) ati Kingsley Olisa la gbo pe won ti wa lorileede Malawi tipe, won ko si nise meji ti won fi n jeun ju ise awon to n ta kokeeni ati igbo lorisirisi lo.

Ohun ta a gbo ni pe se ni okoowo tita kokeeni ati igbo lorileede naa n fojoojumo po so, eyi tijoba orileede naa si lodi si labe ofin ti won gbe kale, idi ni yii ta a gbo pe won fi mu gbigbogun ti awon iwa bayii lokunkundun.

A gbo pe yato si pe won soowo yi lorileede Malawi, won tun n gbe koja lo sawon orileede min in to sunmo won, atawon to jinna an si won.

Ki owo palaba awon meteeta yi too segi lose yii, a gbo pe okan lara awon omo orileede naa to gbajumo daadaa, Riyadh Randera ti won lomo odun merindinlogbon (26) ni naa pelu awon sise yii, inu osu karun un odun yi loun naa si pade iku lojiji.

A gbo pe se Randera gbe kokeeni je lati loo ta a lorileede Brazil, ko too de be la gbo kinni naa tuka mo on ninu, to si gbabe soda sorun alakeji.

Okan lara awon omo Naijiria, Alex Ojukwu ti won loun lo ta tikeeti oko ofurufu fun Riyadh la gbo pe owo ti te, oun lo si salaye fawon olopaa, ko too di pe owo te awon meta won yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI