NITORI IDIBO OSUN: AJO WAEC SUN IDANWO SIWAJU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 20, 2018

NITORI IDIBO OSUN: AJO WAEC SUN IDANWO SIWAJU

Iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi je ko ye wa pe ajo to n sagbateru idanwo asekagba nileewe girama nile Afirika, eka ti lorileede yi, iyen WAEC ti kede sita pe awon ti sun idanwo to ye ko waye lojo Satide to n bo yi siwaju di ojo Satide to n bo lohun.


Fawon to ba mo bi eto idanwo WAEC todun 2019 se n lo si lorileede Naijiria, won yoo mo pe ojo Satide to n bo yi, iyen ojo kejilelogun ni idanwo oyinbo, iyen English fe e waye, ojo naa ni ajo eleto idibo lorileede yi fi idibo gomina nipinle Osun si.

Sugbon ni bayii, ajo naa ti wa a sun idanwo English naa to ye ko waye kaakiri ileewe girama orileede yi si ojo Satide, ojo kokandinlogbon osu yi.


Ori eka ayelujara, iyen Twitter ni ajo naa ti fi ikede yi sita lati le je ki gbogbo aye mo nipa ayipada naa. Nibe naa ni won n in ti je kawon akekoo to n kopa ninu eto idanwo naa mo pe ori ero ayelujara won, iyen www.registration.waecdirect.org ni eon yoo tun ti awon asiko ti won sun awon idanwo to ku si, nitori naa, won ni ki won loo sabewo si ero ayelujara won fun awon ayipada yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI