O MA SE O: AREWA OBINRIN DI AWATI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 24, 2018

O MA SE O: AREWA OBINRIN DI AWATI

SERUBAWON AYEGBAJEJE

Bi e se n ka iroyin yi, inu ibanuje nla ni molebi Okereke wa latarilatari omo won kan ti won pe oruko e ni Jessica Tina se di awati, ti ko si seni to mo ibi to wa titi di bi a ti n sakojopo iroyin yi tan.


Ojo Fraide ose to koja yi, iyen ojo kokanlelogun osu yi la gbo pe Okereke Jessica Tina jade kuro nile, latigba naa ni won ko ti rii ko pada sile.

Bawon kan se n so pe o see se ko je pe awon omo Yahoo lo baje, ki wok si yi fi seso, bee lawon kan n so pe, o see se ko ma fe je kenikeni mo ibi toun wa ni, sugbon ta ko tii le fidi e mule.


Omodun merinlelogun (24) ni won pe Jessica Tina, ta a si gbo pe awon obi e ti loo foro e to awon olopaa leti.

Awon to gbe iroyin naa si AWIKONKO leti fi awon nomba ti won le pe si, bi won ba kofiri Tina sowo ti wa; awon nomba naa ni: 08136767887 ati 08028505034.

Bee ni e tun le kan si ileese olopaa to ba sunmo on yin lati fi to won leti. Olorun ko ni je ka sofo omo. Amin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI