O TAN O: KEMI ADEOSUN TI SA KURO NI NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 15, 2018

O TAN O: KEMI ADEOSUN TI SA KURO NI NAIJIRIA

Bi e se n ka iroyin yi lowo, Minisita foro eto isuna owo tele ri lorileede yi, Arabinrin Kemi Adeosun la gbo pe o ti ba papa bora kuro kuro lorileede Naijiria.


Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe orileede United Kingdom lobinrin naa sa lo.

Be o ba gbagbe, aaro ana, Fraide ni Kemi Adeosun kowe fipo sile gege bi Minisita foro eto isuna, bawon kan si se n kii fun igbese akin to gbe naa, bee lawon kan n bu enu ate lu ayederu iwe eri to n lo naa.

Idi ni yii ta a gbo pe obinrin naa fi pinu lati kuro ni Naijiria, paapaa lati ma se faaye gba oniroyin kankan lati ba a soro.

Ekunrere iroyin idi ti Kemi Adeosun fi kuro lorileede Naijiria lai fi enikeni lara n bo lai pe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI