KAYEEFI NLA: ASIRI ONAREBU TO N FI EJE EEYAN WE NIHOHO LAARIN OJA TU L'OSUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 15, 2018

KAYEEFI NLA: ASIRI ONAREBU TO N FI EJE EEYAN WE NIHOHO LAARIN OJA TU L'OSUN

IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Opo awon to gbo nipa iroyin Onarebu kan ti won lo n soju ekun Ilesa East nipinle Osun, ti won ka mo ibi to ti n we nita gbangba lo si n se ni kayeefi titi dasiko yi pelu bi won se ni eje eeyan lo fi n we iwe naa.


Onarebu Timothy Owoeye la gbo pe lasiko to n we iwe akanse ti won ni babalawo kan yan fun lasiri e tu sowo awon Fijilante.

Gege ba a se gbo, ojo Fraide to koja yi la gbo pe gbajumo Onarebu naa, Timothy Owoeye loo se akanse iwe yi laarin oja kan ti won loo gbajumo daadaa, iyen oja Osunjela niluu Osogbo.

Ibi to ti n we naa lawon Fijilante ti tan ina toosi si loju. Basiri e si se tu sita lo ti bere sii bebe pe ki won da aso asiri boun.

Nibi to ti n bebe naa lawon kan ti fi foonu won ya a fidio, ti won si fi sowo si AWIKONKO, ko da a, ta a gbo pe fidio naa ti lo kaakiri ori ore ayelujara.

Awon kan so pe ona bi egbe oselu APC yoo se pade gbegba oroke nibi eto idibo to n bo lona lo mu ki won maa toju bole babalawo kaakiri.

Pelu iranlowo Kabiyesi, Olosunjela ti Osunjela niluu Osogbo la gbo pe won fi fi sile pe ko maa lo.

PÍN-IN KÁÀKIRI