OJOWU: IYAALE ILE FUN OMO OKO E NI OTA-PIAPIA MU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 26, 2018

OJOWU: IYAALE ILE FUN OMO OKO E NI OTA-PIAPIA MU

Kani kii se pe Ogbeni Kabiru Labbo to je oko Arabinrin kan ti won pe oruko e ni Zulac Kabiru tete gba tesan olopaa lo lati loo fi ejo iyawo e sun ni, o see se ki iyaale ile naa ti na papa bora leyin to pa omo iyawo oko e tan.


AWIKONKO gbo pe, ojo kesan an osu yi ni iyaale ile eni ogun odun naa, Zulac Kabiru fun omo iyawo oko e ni oogun apefon, iyen Ota-piapia mu lasiko ti ko senikeni nile, tomo naa si gbabe kuu danu.

Oku omo naa, nigba ti gboorun enu e lati mo nnkan to je, tabi mu lo tu asiri naa sita pe ota-piapia ni won fun omo osu mejo naa mu.

Basiri yi si se tu lo mu ki Baale ile naa gba tesan olopaa lo lati loo fi to won leti, ki won too de le pada pelu awon olopaa, Zulac ti n palemo awon eru e lati salo.

Abule Danauta nijoba ibile Mariga, ipinle Niger nisele naa ti waye. Tesan olopaa ti ekun Bangi nipinle Niger ni won gbe ejo naa lo.

Nigba to n soro lago olopaa, Zulac so pe kii se pe oun mon on mo pa omo naa danu, sugbon nitori pe oko oun ko gbonran soun lenu lati ma feyawo min in lo je koun pa omo iyawo e naa.

AWIKONKO gbo pe latigba ti Labbo ti feyawo tuntun naa ti won pe oruko e ni Rukaiyat ni wahala ti n sele, ko da a, ta a gbo pe opo awon eeyan ni won ti da sii, sugbon ti won ko rii yanju.

Zulac tesiwaju pe latigba ti Rukaiyat ti wole ni kii tii teriba foun, to si maa n yeye oun nita gbangba, idi ni yii toun fi n wa ona lati daa loro, lati le ko logbon bi won se n niteriba nile oko

Bee lo tun so pe oun ko mo igba toun fun omo naa loogun apefon mu, bo tile je pe o ti wa lokan oun tele, sugbon sibe, oun gba pe ise esu ni, ati pe iwa toun hu naa buru jai, to si ni ijiya, sibe naa, oun be ijoba lati dariji oun.

Agbenuso fawon olopaa ipinle Niger, Muhammad Abubakar fidi isele naa mule, to si seleri pe Zulac ko ni pe e foju bale ejo lati gba idajo to to sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI