OLUDASILE SOOSI MFM, DOKITA OLUKOYA GBE SOWORE ATI SAHARA REPORTERS LO SI KOOTU LORI ESUN IBANILORUKO JE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 4, 2018

OLUDASILE SOOSI MFM, DOKITA OLUKOYA GBE SOWORE ATI SAHARA REPORTERS LO SI KOOTU LORI ESUN IBANILORUKO JE

...Bilionu Mewaa Naira Ni Won N Beere Lowo E Gege Bi Owo Itanran

Bi e se n ka iroyin yi, ni inu oludasile soosi Ori Oke Ina ati Ise Iyanu (Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) ko atawon alabasise po e ninu soosi naa ko dun si oludije sipo Aare orileede Naijiria ninu eto idibo odun 2019 to n bo lona, iyen Ogbeni Omoyele Sowore ati ileese iroyin e, Sahara Reporters.


Ko si nnkan meji ta a gbo pe o fa aidunnu naa bi ko se tawon iroyin ayederu ti won ni ileese Sahara Reporters nko nipa soosi naa, pelu erongba lati ba oruko oludasile ati soosi naa je patapata.

Gege bi a se gbo, lati odun 2013 la gbo pe ileese iroyin Sahara Reporters, iyen Sahara Reporters Incorporated ti bere sii gbe awon iroyin eleje nipa soosi naa kaakiri ori ero ayelujara.

A gbo pe latigba naa ni awon alase ati apase soosi naa ti bere sii ba oludasile ileese iroyin Sahara Reporters, iyen Omoyele Sowore soro pe ko pa iroyin naa re, ko si yee gbe awon iroyin to jinna si otito nipa won sori ero ayelujara, sugbon ti won ni okunrin naa ko gbo.

AWIKONKO gbo pe kaka ki okunrin naa ati ileese e dekun lati ye maa gbe ayederu nipa ilu mon on ka ojise Olorun naa, iyen Dokita Daniel Kolawole Olukoya ati soosi e, se lo n tera mon gbigbe awon iroyin eleje nipa won kaakiri.

Aimoye igba la gbo pe Dokita Olukoya atawon alase ati apase soosi MFM ti kowe ifesukan si Sowore ati ileese Sahara Reporters pe ko pa awon iroyin naa re, ko si ye e gbe awon iroyin ti ko ba ri aridaju won kaakiri.

Bee la tun gbo pe lai pe yi ni soosi naa tun kowe sileese naa lati pa gbogbo awon iroyin naa re laarin ojo meje pere, ati pe lai je be, awon yoo fesun ibaniloruko je kan an nile ejo, ti won si lokunrin naa sebi eni pe oun ko ri awon leta naa gba.

Idi ni yii ti won ni won fi gbe Sowore ati ileese e, Sahara Reporters Incorporated lo si ile ejo giga to wa niluu Uyo, iyen nipinle Akwa Ibom.

Ninu iwe ipejo naa ti nomba e je HU/250/2018 la gbo pe Incorporated Trustees ti soosi Mountain of Fire and Miracles Ministries lo je olufesun kan akoko, ti Dokita Olukoya sikeji e.

Ninu iwe esun naa ni won tun ti n beere fun owo oni bilionu mewaa (N10BN) naira gege bi owo itanran, bee naa ni won tun beere fun ase ileejo pe ki Sahara Reporters pa gbogbo awon iroyin naa re.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI