WON KA PASITO MO IBI TO TI N BA OMO SOOSI E SUN LORI OKE N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 3, 2018

WON KA PASITO MO IBI TO TI N BA OMO SOOSI E SUN LORI OKE N'IBADAN

Titi di bi e ti n ka iroyin yi, iyalenu loro pasito kan ti won pe oruko e ni pasito Osho ti won ka mo ori okan lara awon omo soosi e ti won jo n ba ara won sun karakara ninu igbo.


Gege ba a se gbo, obinrin naa ti won pe ni Arabinrin Ajibade la gbo pe o lo si ori oke ti pasito naa wa lati loo gbadura ati awe olojo meta, sugbon to je pe kaka ko kojumo nnkan to ba lo, nnkan min in lo n se.

Ohun ta a gbo ni pe gbara ti Arabinrin Ajibade ti de si ori oke naa ti won ni ilu Ibadan lo wa ni won lawon kan ti bere sii fura sii, paapaa pelu isesi oun ati pasito Osho.

Idi ni yii ta a gbo pe awon eeyan naa fi bere sii so won lowo-lese lati mo nnkan to pa won po, sugbon ta a gbo pe asiri won pada tu sita lopin ose to koja yii.


Se la gbo pe inu igbo kan nitosi ori oke naa ni Pasito Osho ati Arabinrin Ajibade gbe ara won lo, ti won si n gbe nkan si ara won labe, ti kinni in naa si n dun mo won karakara.

Lara awon to topinpin awon mejeeji de inu igbo naa la gbo pe o gbe foonu e lati fi ya won nile ti won ti n ko ibasun funra won karakara.

Nigba to maa to iseju die tawon mejeeji ti n ba ara sun ni eni naa je ki won mo pe oun ti n wo won tips, Bi pasito naa si se rii pe wahala nla ni fidio naa yoo je fawon mejeeji lo mu ko fe e fipa gba a, ko si paare, sugbon tiyen so oro naa di ariwo.

Iyalenu lo je fun opo awon to wa a gbadura ni ori oke naa, to mu ki won maa gbe pasito naa se epe nla-nla, ti won si n bu enu ate luu pe awon iranse esu ti won n foruko Olorun boju ni.

Lesekese la gbo pe won ti gbe fidio naa sori ero ayelujara, tawon eeyan si bere sii pin in kaakiri lati le je ki won mo iru ori oke ti won yoo ti lo maa gbadura dasiko yii.

Sa o, titi di Bi a ti sakojopo iroyin yi tan la gbo pe Arabinrin Ajibade to dagbere ko too kuro nile e pe oun fe e loo gbadura ati aawe ni ori oke si ba papa bora, ti ko si seni to le so ibi to gba lo.

Bee la gbo pe won ti da Pasito Osho duro lori oke naa, toun naa si ti ba papa bora bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI