OPE O: AWON ADIGUNJALE META TA TERU NIPA L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 23, 2018

OPE O: AWON ADIGUNJALE META TA TERU NIPA L'OGUN

SERUBAWON AYEGBAJEJE

Kani kii se pe awon olopaa ipinle Ogun, ti ekun Owode Egba tete gbera nigba ti won gbo pe awon adigunjale kan tun ti n so'se lagbegbe Fidiwo, loju ona Eko si Ibadan lojo Abameta Satide to koja yi, iyen ana, o see se ki okete won tun ti boru salo gege bi won se maa n se.


Ohun ta a gbo ni pe awon adigunjale naa ti ko din ni mefa la gbo pe won digun loo ba obinrin kan to n ta eran igbe, Arabinrin Jumoke Ogunbade.

Nibi ti won ti n ja a lole, la gbo pe awon kan to n koja lo ti ri won, awon naa ni won te ileese olopaa laago lati fi to won leti.

Lesekese tiroyin naa ti te DPO Owode Egba, Sheu Alao leti lo ti ko awon olopaa abe sinu moto, ti won si sare lo sibe.

AWIKONKO gbo pe fun bii ogbon iseju lawon adigunjale naa fi koju ibon sawon olopaa yii, toro naa si da bi oogun abele keji, sugbon leyin o reyin, ibon pada ba meta ninu won.


Lesekese lawon meteeta ti ku danu, bawon to ku si se rii pe meta ninu won lawon olopaa ti ran lo sorun apapandodo lawon naa ti na papa bora.

Ibon orisi meta ati opolopo ota ibon, to fi mo owo egberun mewa ati igba le logun (10,220) naira ni won ba lara won.

Ahmed Iliyasu ti wa pase pe kawon olopaa naa tubo sewadi lati rii pe owo te awon odaran to ku to salo, o si gbawon araalu lamonran pe kawon naa bere ise ojulalakanfinsori ki eto aabo le tubo peye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI