BOKO HARAM YINBON PA AREWA OBINRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 16, 2018

BOKO HARAM YINBON PA AREWA OBINRIN

Ninu osu keta odun yii ni awon janduku egbe BOKO Haram kogun ja gbegbe kan ti won n pe ni Rann, Kala Balge, nibe lowo won ti te awon osise ajo Red Cross, iyen alagbelebu pupa, ninu eyi ti Hauwa Liman ti wa lara won, ti won si ti yinbon pa a bayii.


Egbe BOKO Haram kan ti won pe oruko won ni Islamic State West Africa Province (ISWAP), lo yinbon pa arabinrin naa. Won ni seni won so o lokun lowo seyin, ti won da a kunle, ti won si se bee yinbon fun un lateyin.

Saaju asiko yii ni won ti koko pa enikan danu, Saifura Ahmed loruko e, lara awon osise Red Cross ni.

Ni kete ti won ti pa a ni egbe alajangbila yii ti so fun ijoba apapo wi pe ti won ko ba fun awon lohun tawon n fe, nise lawon yoo pa Hauwa Liman naa.

Ana Monde yii ni gbedeke ojo ti won fun ijoba apapo tan, nigba ti ile yoo fi mo laaaro Tusde oni, ariwo to gbalu kan ni pe, won ti gbemi obinrin osise ajo Red Cross ohun.

Esun ti won fi kan Saifura ati Hauwa enikeji e ti won ti koko pa tele ni pe, won pa esin Islam ti, won ba ajo agbelebu lo, eyi to mu egbe alajangbila ohun ka won kun odale.

Ijoba orile-ede yii ti bu enu ate lu iku ojiji ti won fi odomobinrin naa. Ninu oro ti minisita feto iroyin, Alhaji Lai Mohammed fi sowo lati ilu London to wa lo ti so pe iku obinrin naa ba ijoba apapo lojiji, ati pe iyalenu nla lo je wi pe awon alajangbila ohun le pa a pelu gbogbo akitiyan ti ijoab sa lati ri i pe won tu oun atawon yooku e sile nigbekun awon odaran ohun.

Te o ba gbagbe ko ti ju osu kan lo ti awon alajangbila yii sekupa Saifura Ahmed, latigba naa ni won si ti fun ijoba apapo ni gbedeke igba ti won yoo tun pa elomi-in ninu awon osise ajo Red Cross ti won wa nigbekun won.

Lara awon to si wa nigbekun won bayii ni Alice Ngaddah, elesin Kristeni ni, bee lo tun je osise ajo agbaye kan to n je UNICEF.

Bakan naa ni Leah Sharibu, okan lara awon omoleewe Government Girls’ Science and Technical College, niluu Dapchi, ipinle Yobe State. Eeyan Aadofa (110) ni won lo ji gbe nileeewe ohun lojo naa, obinrin si ni gbogbo, iyen lojo kokandinlogun osu keji odun yii.

Leah Sharibu nikan lo si wa ni akata won, nigba ti won ti tu awon yooku sile.

Ohun ti won lo fa a ti won ko se fi i sile ni bi odomobinrin ohun se ko lati gba esin Islam, won lo so pe esin Kristeni toun n se loun ba duro. Ohun ti won lo bi awon alajangbila yii ninu niyen o, ti won ko fi ju u sile nigba ti won yonda awon yooku e fun ijoba.

Ni bayii, leyin ti won pa Hauwa, ohun ti won n so ni pe, Leah Sharibu ti di eru awon bayii, ati pe gbogbo ara to ba wu awon pata la won yoo fi omo naa da.

PÍN-IN KÁÀKIRI