PETER OBI DI IGBAKEJI ATIKU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 13, 2018

PETER OBI DI IGBAKEJI ATIKU

“Pelu imo ati iriri alailegbe ti gomina tele nipinle Anambra, Peter obi ni, yala ninu ise ijoba tabi aladaani atawon imo to ti ni kaakiri agbaye, idi niyen ti mo fi mu un gege bi igbakeji mi, ati pe ajpsepo wa yoo wulo dada fun ilosiwaju Nigeria.”

Ninu atejade kan ti Otunba Gbenga Daniel, eni ti se oludari ipolongo ibo fun Alhaji Atiku Abubakar lo ti fidi oro yii mule. 

O te siwaju pe, awon ohun amuye ti gomina tele nipinle Anambra ohun ni; lo mu egbe oselu PDP fowo si i lati je igbakeji Atiku ninu ibo aare lodun to n bo. 
O ni, “Ohun to mu Atiku ati egbe oselu PDP yan Peter Obi' gege bi eni ti yoo dije-dupo  Aare pelu e lodun to bo ni bi okunrin naa se wa lara awon odo orile-ede yii ti won lami-laaka ninu iriri orisirisi, paapaa eyi ti gomina tele naa ti ni ninu ise ijoba ati ti aladani. 

O ni “Peter Obi ni imo kikun ti a ba n so nipa oro aje aladanla ati alaboode, yala nile yii ni abi loke okun; bee gege lo tun je eni ti imo e kun, ti a ba n so nipa eto isuna owo, eyi ti yoo sanfaani nla fun ilosiwaju orile-ede yii, paapaa niru asiko ti Nigeria wa bayii.
O ni, ajosepo awon mejeeji yii ni yoo da orile-ede yii pada si ona to ye, ti idagbasoke alailegbe yoo ba eto oro aje wa, ti isokan yoo si wa pelu. 
Ninu atejade ohun lo ti so pe; ojo kokandinlogun osu keje ni won bi Peter Obi lodun 1961. Ileewe Christ the King College, l’Onitsha lo lo, leyin e lo te siwaju lati kawe si i ni University of Nigeria, Nsukka nibi to ti kawe gboye Bachelor of Arts in Philosophy. 
Bakan naa lo tun kawe lorisirisi lawon ileewe wonyi: Lagos Business School, Harvard Business School, London School of Economics, Columbia Business School, Institute of Management, Switzerland, Kellogg Graduate School, Oxford University and Cambridge University.” 
Ti a ba n so nipa ise ijoba, opolopo eka  ileese ijoba lo ti sise pelu, lara won ni: okan lara awon to n sasaro lori eto oro aje fun ileese Aare (Member, Presidential Economic Management Team) , igbakeji alaga fun apejo awon gomina (Vice-Chairman, Nigeria Governors' Forum); Alaga fun awon gomina apa iha Guusu-Ila-OOrun (Chairman, South-East Governors' Forum), bakan naa lo tun ti se gomina ipinle Anambra ri. 
Oguna gbongbo kan ni Peter Obi, eni to ni imo kikun nipa ise ijoba ati ise aladaani ni pelu. Oun naa tun ni alaga fun ileese Board of Security and Exchange Commission (SEC); bakan naa lo tun je alaga tele fun awon ileese yii; Fidelity Bank PLC; alaga tele ni banki Guardian Express Mortgage Bank; oun naa tun ni alaga Future Views Securities; alaga tele fun Paymaster Nigeria; alaga tun ni ni Next International Nigeria; oun naa tun ni alaga won tele ni banki Guardian Express Bank PLC; oga agba tun ni lawon ileese wonyi: Chams Nigeria PLC;, Emerging Capital: ati Card Centre PLC. 
Lara awon ti yoo dije dupo aare lodun to n bo ni Alhaji Atiku Abubakar, eni to ti figba kan je igbakeji aare orile-ede yii ri laye ijoba Obasanjo. Oun naa yoo dije-dupo aare lodun 2019, bee lo si ti mu igbakeji e bayii, Peter Obi, omo ipinle Anambra, eni to ti se gomina tele ri nipinle ohun.

PÍN-IN KÁÀKIRI