Owo olopaa
ipinle Eko ti te odomokunrin eni odun marundinlogbon kan, Yinusa Olowu ti won
fesun kan pe o fa idi omodun meta ti ileewe Smart Kids Say to wa lagbegbe
Bariga nipinle Eko.
Gege ba a se
gbo, ise birikila ni won so pe Yinusa n se. Ojo Tusde to koja yi lasiri e tu leyin
ti won ni iya omo naa loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si gbe omo naa
loo sayewo.
Ileewosan ti
won gbe omodebinrin ta a foruko bo lasiri naa lo ni won ko ti je ko ye won pe
idi omo won ti faya perepere.
AWIKONKO gbo
Yinusa loo wo ore e to ni ileewe naa, Sodiq Showunmi lojo naa, nibe lo si ti
fipa bomodebinrin yi sun, to fa idi e ya.
Titi di bi e
ti n sakojopo iroyin yi lawon to gbo si oro naa si n gbe Yinusa se epe
rabande-rabande latari iwa buruku to hu naa, ta a si gbo pe ileese olopaa ti seleri
pe awon yoo foju e bale ejo lai pe.