Ko din ni meje lawon alaisan foniku-fola-dide
(sickle sell anaemia) ti ileewosan meji otooto nipinle Anambra ti ti mole
latari bi won ko se rowo san latari iwosan ti won fun won.
Alaga egbe
kan to n ri soro awon to ni aisan naa, (People Living with Sickle Cell Disorder
(PLSD)), Arabinrin Aisha Edward lo fidi oro yi mule lojo Tosde to koja yi
lasiko to n bawon oniroyin soro lagbegbe Nanka to wa nijoba ibile Orumba North nipinle
Anambra.
Egbe naa so
pe ona ti ko bofin mu lawon ileewosan naa gba lati ti awon alaisan naa mole,
ati pe iwa odaju lawon ileewosan naa hu, won ko si laani eleran ara bii ti won.
O loun lo
sileewosan kan lati wo awon to ni aisan naa nibe, ti won si n je ko ye oun pe
awon alase ileewosan naa ti awon eeyan mole, won ko fi won sile lati lo sile
won leyin ti won gba itoju, latari owo tabua ti won ko fun won, eyi ti won ko
ri san an.
O ni igbese
lati da si oro naa ti bere, ati pe oun mo pe iru awon eeyan bayii si ku lawon
ileewosan kookan bee, sugbon toun yoo sewadi won lati tese ofin oro naa.