EYI NI BI FAYOSE SE BO LOWO EFCC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 30, 2018

EYI NI BI FAYOSE SE BO LOWO EFCC

Lati ojo Wesde ose to koja nile ejo giga kan niluu Eko ti fi aaye sile pe ki Gomina ana nipinle Ekiti, Peter Ayodele Fayose lo wa oniduro meji ti yoo san aadota milionu lati fi gba beeli e lowo ajo to n gbogun ti sise owo ilu kumokumo, iyen EFCC latari awon esun ti won fi kan an pe o si agbara lo, o si tun lo owo ipinle naa lona ti ko ye.


Kii se pe ajo EFCC dee de fi Fayose pamo latigba naa, idi ni pe ko ri awon oniduro meji naa, sugbon ofin ti adajo naa fi sile ni pe awon oniduro naa gbodo je olugbe ipinle Eko, won si gbodo ni dukia nibe, bee ni won gbodo fi iwe owo ori odun meta ti won san nipinle naa sile.


Latigba yi ni Ayodele Fayose ti n wa eeyan naa ti yoo duro fun un, sugbon ana, Monde to koja yi lawon meji naa yoju, ti won si ko gbogbo nnkan ti adajo pase re sile.


Be o ba gbagbe, ojo kerindinlogun osu yi ni Ayodele Fayose ko gbogbo eru e, to si gba ileese EFCC lo niluu Abuja lati loo da won lohun bi won se ranse pe e lati wa a salaye bo se na awon owo kan ti won fesun e kan an.

Ana lo si je ojo ketala to ti wa lahamo ajo EFCC. Lara awon to loo pade Ayodele Fayose ni adije sipo gomina nipinle Ogun, Onarebu Oladipupo Adebutu.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI