NIGERIA KO SE E FI SAA ISAKOSO KAN TUN SE - BUHARI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 30, 2018

NIGERIA KO SE E FI SAA ISAKOSO KAN TUN SE - BUHARI PARIWO SITA

Aare Muhammadu Buhari ti rawo ebe sawon omo orileede Naijiria pe ki won fi oju aanu wo oun lati pada dibo foun leekeji nitori pe ayipada toun seleri fun won lodun 2015 ko se e fi saa isakoso kan soso se.


Ilu Eko ni Aare Muhammadu Buhari ti soro yi lasiko to n bawon eeyan soro nibi ayeye eto okoowo odun karundinlogorin (75th) eyi ti Island Club se lojo Monde ana.

O ni yoo gba ju saa isakoso kan lo lati le se awon atunse to ye lati mu orileede Naijiria lo si ipele to ye ko wa, ati pe lati yoo gba ju idibo eekan soso lo ki ileri toun se too le di mimuse.

Buhari so pe ayipada tijoba oun seleri kii ayeye ojo kan soso, bi ko se pe nipele-nipele ti yoo gba akoko ni, nitori naa kawon omo Naijiria dibo yan oun leekeji fun odun merin min in.

Bee lo so pe lai pe lawon igbese toun ti gbe laarin odun meta aabo lati mu atunse deba orileede Naijiria gege boun see seleri e ko ni pe ti yoo fi bere sii farahan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI