Ibikunle Aduragbemi
Okan lara awon adije sipo asoju-sofin (House of Reps) niluu Abuja lodun 2019, lati ekun Abeokuta South, Attorney Kehinde Adebayo Shomoye ti fi oko oro ranse sawon oloselu orileede Naijiria, pelu bi won se n fi etanje bawon araalu se, ti won kii sii jise ti won ran won.
Adebayo Shomoye to fe e jade labe egbe oselu Accord lo soro yi lasiko to n b'AWIKONKO soro ni sileese egbe oselu naa to wa lagbegbe Ita-Oshin, Abeokuta.
Ninu oro re, o ni "Kii se pe mo dee de pinu lati jade dupo yi, United States ni mo ti wa fun ojo pi pe, mo si ti nii lokan pe maa darapo mo oselu lojo kan, idi si ni pe mo fe e wa ninu eto oselu nitori pe ona adojutini ti won fi n se oselu lorileede yi ni mo fe e yi pada. Ipinu rere lati rii pe eto oselu awaarawa pada bo sipo lo mu ki n jade lasiko yi, nitori pe a ko le la oju sile, ka maa wo bi won se n ba ijoba je.
"Bi e ba wo awon oloselu lawon egbe oselu to loruko daadaa, e maa rii pe nnkan ti won n se lasan ni pe won fe e je gaba lori ohungbogbo. Kaka ki won gbe eto isejoba awaarawa laruge, nnkan to je won logun ni pe ki won maa lagbara sii, eyi ti ko si ri be lawon orileede to ku, o je nnkan itiju.
"O tun je nnkan itiju pe won tun n tako awon to fe e jade dupo labe egbe oselu won, kaka ki won maa se ni kooro yara, ita gbangba ni won tun ti n so o lai ni itiju.
"Mi o ti e ki n fe e teti gbo iroyin mo, nitori pe orisirisi oyinbo nla-nla le ma maa gbo, to si je pe oro kan soso ti mo ti n gbo lati kekere mi naa ni mo si n gbo titi dasiko yii, ti ko seni to fe e ronu nnkan tuntun.
"Looto ona to jin ni, idi ni yii tawon to ni erongba rere fi maa n pada nigba ti won bere, to si maa n fawon ti ko nife omo orileede Naijiria won dokan de ipo ti won ba ran won loo soju, anfaani naa ni won n lo lati fi se nnkan to wu won lokan lai ro tawon to ran won lo.
"Ipinu idagbasoke, ipinu lati mu orileede yi lo siwaju, lati tan isoro awon eeyan, lati mu idagbasoke ba eto ilera, eto eko, oju ona to ja geere ati lati gbe ijoba ti yoo se nnkan to ye sipo ni mo ni fawon eeyan mi."
Nigba to n soro lori idi to fi yan egbe oselu Accord laayo, Shomoye so pe ko si nnkan meji ti ko je koun lo sawon egbe oselu bii APC ati PDP bi ko se pe oun ko ni bilionu toun fe e na nitori ipo, nitori pe eni ti ko ba ti le gbe bilionu sile, won ko nii fun laaye.
Bee lo so pe iru eni to ba ni nnkan to fe e se ko ni lanfaani lati loo bawon eeyan soro nipa ipinu to ni fun won, toun si rii pe anfaani ni legbe oselu Accord je foun lati bawon eeyan soro.
O tun fi kun un pe boun ba lo sawon egbe oselu yi, se ni won a pa erongba rere toun ni patapata, titi kan ojoola oun ni won a fi oselu parun, toun ko si fe ko ri bee.
Bakan naa nipa ti ajo INEC, Shomoye so pe "Bi e ba wo eto idibo to waye nipinle Osun, e maa rii pe onikaluku lo n soro pe ko te won lorun, gbogbo wa la si ni ojuse lati rii pe INEC se nnkan to ye ki won se lati rii pe idibo lo gege bo se ye."
Lakotan nigba to n gbawon eeyan lamonran, o ni o se dandan kawon araalu rii daju pe won ko tun pada yan awon to ti puro fun won sipo leekeji, nitori pe won ko ni nnkan gidi lati se, nitori naa ki won yan awon oju tuntun to ni erongba rere sipo.
No comments:
Post a Comment