E NI LAATI JE ADARI TOOTO - ANN GBAWON ADIJE LAMONRAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 8, 2018

E NI LAATI JE ADARI TOOTO - ANN GBAWON ADIJE LAMONRAN

Alaga egbe oselu Alliance for New Nigeria, ANN, nipinle Ogun, Komureedi Mike Adekunle ti gbawon adije ti won dibo yan nibi idibo abele, iyen pamari egbe won to waye lojo Tosde to koja yi niluu Abeokuta pe ki won je adari tooto tawon araalu yoo ri gege bi awokose rere.


Komureedi Adekunle ni, eni to ba mo pe oun fe se adari ni eka yoowu gbodo mura lati se bi eru fawon to n bo leyin, nitori naa, bi won ba de ipo ti won n lo lodun 2019, won ko gbodo jawon araalu kule nipa ileri ti won se fun won.

O ni bo tile je pe egbe tuntun ni egbe won, to si je pe odo ni gbogbo won patapata to wa ninu egbe naa, to fi mo awon adije won, sibe, gbogbo igbaradi lawon ti pari lati rii pe awon jawe olubori lodun 2019.

Okunrin naa tun tenu mon on pe asiko ti to fawon odo lati gbajoba lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun nitori pe awon ko le la oju sile kawon agbaagba nidi oselu fi ojo iwaju awon ta tete, idi ni tii tawon yoo fi sa gbogbo ipa won lati rii pe awon gba eto won.

Ninu oro agbenuso fegbe naa, Ogbeni Lugard Ola-Raheem lo ti gbawon eeyan lamonran pe ki won m se sa seyin ninu eto oselu to n lo lowo yi, paapaa eto idibo to n bo lona lati le rii pe won ja fun eto ara won.

O ni kii se pe keeyan gba kaadi idibo alalope gangan lo se koko, bi ko se pe ki won ma se gbawon oloselu oniro laaye lati tan won je nitori pe pupo ninu won ni won n jade lati tan awon araalu je pelu awon ileri ori ahon ti won n se fun won, nitori naa ki won kopa to joju lati rii pe eto won te won lowo.

Lara awon to fe e jade dupo labe egbe oselu naa ni: Ogbeni Ademola Ogunbanjo toun fe e di gomina; Akeem Amosun ati Lekan Bamiro tawon fee dupo omo ile igbimo asoju-sofin (House of Reps) lati ekun Abeokuta South Constituency ati Ijebu Central Constituency.

Awon omo ile igbimo asofin ipinle naa ni: Solomon Enilolobo, Abeokuta South II; Ogunkoya Mayowa, Ifo I; Abiodun Sorunke, Ado Odo Ota I; Oliwo Omotayo, Ado Odo Ota II; Shittu Adedayo, Ijebu North 1; Agbabiaka Odunayo, Obafemi Owode.

Awon yooku ni: Bukola Ogunsanwo, Sagamu 1; Adelaja Opeyemi, Remo North; Similoluwa Osifeso, Odogbolu ati Abiodun Olugbamila, Yewa North.

Nigba toun naa n soro nipa imurasile, adije sipo gomina ti won fa kale, Ogbeni Ademola Ogunbanjo so pe bo tile je pe kaakiri ijoba ogun to wa nipinle Ogun lawon ti lo, sibe iyen ko ni kawon ma tun pada loo bawon soro nitori pe idibo pamari tawon n duro dee naa lo ti pari yii.

O ni looto, omode loun nidi oselu nitori pe osu meje seyin loun darapo, sugbon igbaradi oun ti fi han pe egbe awon yoo jawe olubori, paapaa bo se je pe asiko odo lawon wa yii.

O tun so pe idi toun fi yan egbe oselu naa laayo ni pe erongba oun ati ipinu toun ni lati dupo naa ba ti egbe oselu ANN lo, idi ni yii toun fi darapo mo won, ati pe oruko lasan lawon egbe oselu to ku bii PDP, APC, AD, SDP abbl lori, tawon araalu ko fi oju eeyan gidi wo won.

Nipa ti ajo eleto idibo, INEC, Ogunbanjo so pe o see se ki ajo eleto idibo ti ri awon asise won nipa eto idibo ti won se koja nipinle Ekiti ati Osun, sugbon iyen ko ni koun ma nigbagbo ninu won, ati pe awon yoo tubo maa gbawon niyanju lati fi otito se nnkan won ni.

Bee lo soro lori bi won se n fowo ta ibo lojo idibo, Ogunbanjo so pe ko ba ofin orileede yi mu, INEC si gbodo rii pe awon towo palaba won ba segi gbodo foju bale ejo lati gba idajo won, ati pe igbagbo toun ni ni pe awon eeyan yoo gba owo sugbon won ko nii dibo fun won.

Nigba to n soro nipa ipinu e, o ni egbe ti won kii se egbe ojelu, nitori pe awon ko ji owo ijoba ri, idi ni yii tawon fi fe e lo gbawon araalu sile ninu iya to n je won, bii eto eko, eto ilera atawon min in to n je awon araalu niya lawon se da egbe naa sile, ati pe imo ati oye tawon n gbe bo, fun itesiwaju si.

Awon eleto idibo to wa nibe ni: Afolabi Ebenezer Odetayo, alaga; Arabinrin Titi Oduneye, akowe; Ogbeni Talabi Zacheus; Ogbeni Taiwo Olubode ati Arabinrin Itta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI