OSELU NI WON FI DA EGBE AFENIFERE SILE – DOKITO OMONAYAJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 3, 2018

OSELU NI WON FI DA EGBE AFENIFERE SILE – DOKITO OMONAYAJO

Alaga egbe Igbimo Agba Yoruba, Dokito Muiz Omonayajo ti so pe erongba ti won fi da egbe naa sile yato patapata si erongba ti won fi da egbe Afennifere sile. Lai pe yi ni Dokito Omonayajo soro yi lasiko to n b’AWIKONKO soro ninu ile e to wa niluu Abeokuta. Nibi iforowero naa lo ti so nipa irin ajo aye e, ati bo se di alaga egbe naa nipinle naa. Bakan naa lo tun so nipa Egbe OPC ti Aare Ona Kakanfo, Otunba gani Adams da sile ati ajosepo egbe naa. E ka bi iforowero naa se lo.

Dokito Omonayajo
AWIKONKO: Oruko yin lekunkunrere ati bi e se je?
OMONAYAJO: Oruko mi ni Dokito Muiz Ajani Adeleke Omonayajo, alaga Igbimo Agba Yoruba nipinle Ogun.

AWIKONKO:  Ka too tesiwaju, nje a le mo die nipa irin ajo yin ki e too di alaga?
OMONAYAJO: Ti e ba fee mo itan nipa igbesi aye mi, e maa nilo lati se iwe itan nla meji, to maa kun repete. Opolopo mo mi, sugbon o ni iwanba nnkan ti won mo nipa mi, sibe, maa so die ninu e fun yin nipa bi mo se lo sileewe. Ilu Abeokuta ni won ti bi mi ladugbo Ilugun. Omo Ilugun nile Agbunrin ni baba mi, nitori pe agboole Agbunrin yen, awon oni-Sango lo po nibe, nitori esin Musulumi toun gba, lo se kuro nibe lo si odi keji. Keu la maa n koko ke ninu idile ka too lo bere ileewe. Baba-baba mi je Oke Ona, iya-baba mi je Egba Alake; Baba-iya mi je Gbagura, Iya-iya mi je Owu, origun mereerin Egba ni mo fi tan. Ileese irina oju-irin ti orileede Naijiria (Nigerian Railways) ni baba mi ti sise, nigba ti won gbe baba mi lo siluu Guso ti won so di Gusau bayii, ibe ni mo ti bere ileewe alakobere nileewe Aguda (Catholic School), ibe ni won ti se iribomi fun mi.

Bi baba mi se gbo, lo ti mu mi kuro nibe, to si mu mi lo si ileewe Anglican. Ibe ni mo ti nife si esin Kristeni. Nigba ta a gbominira ni baba mi pada wa siluu Abeokuta. Igba ti baba mi pada sile ni mo sese wa a bere ileewe giga, iyen Methodist niluu Igbo-Ora. Igba tawon to mu esin igbagbo wo Naijiria (Missionaries) fe e pada si orileede won, ni won fa ileewe naa le awon olori niluu Igbo-Ora lowo, ibe ni mo ti bere esin Kristeni ni pereu, nitori pe oga ileewe yen feran mi, o si je elesin igbagbo. Igba ti mo kuro nibe, mo lo si Federal School of Science ni Onikan, l’Eko, ibe ni mo ti kuro ti mo fi loo sise ni Western Region, ileewe yi ni mo tun pada si lati loo sise Tisa, ko too di pe mo lo si Yunifasiti lati look o eko nipa Oogun (Medicine). Bi mo se wa nileewe yi, ni mo tun n sise peepeepee, ti ko si di ara won lowo. Mo sise ni Leonart to wa ni Ojota niluu Eko, mo sise ni National Bank Marina.

Ko pe ti mo jade ni Yunifasiti, ti won fi da ipinle Ogun sile, ipinle Kwara ni mo ti loo se Agunbaniro mi, mo isse nibe, mo si gba awoodu, nitori pe mo gbe eto kan kale ti mo pe ni Baby Week Show, eyi ti mo fi n se itoju awon araabule yen. Igba ti mo kuro nibe, ni osibitu ti mo ti sise nigba naa gbe mi lo sodo Oloogbe Olabisi Onabanjo gege bi dokito won fun odun merin, igba to ya, ti Onabanjo kuro nipo, mo tun je dokito fun Jenera Oladipo Diya, ko too di pe won gbe mi lo siluu Ilaro. Igbe ti mo kuro nibe ni won tun gbe mi wa si Ministry gege bi akowe Mo ti sise ni ileewosan ijoba to wa ni Sagamu labe Baba Ogunnekan. Igba ti oga mi feyinti, won fi mi se alakoso fidihe gege bi eleto ilera nipinle Ogun (Ogun State Acting Chief Medical Officers). Mo tun lo si ASCON (Administrative Staff College of Nigeria) ni Badagry nibi ti mo ti ko Research Methodology

Igba to ya, won fi mi se Head of Planning Division, ibe ni mo wa kawon banki agbaye (World Bank) to o de lati ya awon ipinle lowo lati maa fi seto ilera, emi ni won ti sibe lati mojuto o. Awon banki agbaye yi ni won fun mi niwe eko ofe lati loo kekoo loke okun, iyen University of Leads, Britain. Igba ti mo setan nibe, mo pada sile, bi o se n de ni won fi mi se Director Planning Research and Statistics nipinle Ogun, emi ni mo je eni akoko. Ibe lawon oyinbo Japan tun ti de, ti won fun mi ni eko ofe niluu Tokyo, igba ti mo de, ijoba apapo yan mi gege bi okan lara awon to maa lo so asoyepo lati gba owo ele ni banki agbaye (World bank Loan), iyen ni Washington DC. Igba yen, Dokito Makanjuola ni alakoso ni Ministry of Health, ti emi si je alakoso ni eka eto ilera tipinle Ogun (Ogun state Ministry of Health).

Leyin ta a setan nibe, ta a de, won ni ka wa gba eyawo naa, mo wa a ri pe ele (interest) ti won fe e gba lori eyawo yen ti po ju, mo so fun won pe owo ti won n fawon ara oke oya, pe kawa naa gba, iyen African Development Bank Loan, idi ni yii ta a fi so gbogbo awon ileewosan to wa nipinle Ogun di jenera (General Hospital). Ibi ta a ti lo soro nipa eyawo yen niluu Abidjan ni won ti so pee mi ni ki n je alakoso (Project Manager). Asiko yen aawo wa laarin emi ati Gomina Sam Ewang nitori pe ona to fe e ka gba ko ba ilana awon to ni owo yen mu, won si ti towo bowe adehun pelu emi, ti won gba mi gege bi osise ti kii se osise ijoba taara (secodnment), eyi ti ko ye opolopo awon eeyan. Won dite nigba naa, sugbon Olorun ti mi leyin. Mo gbe won lo si kootu, ile ejo si pase pe ki won san gbogbo owo ti won je mi, won si san an. Ibe ni mo ti feyinti.

Leyin ti mo feyinti, mo loo sinmi fungba die, ko too di pe mo loo se oselu. Igba ti mo kuro nidi oselu ni won wa a pe mi pe ki n wa a se alaga Igbimo Agba Yoruba fun won nipinle Ogun, iyen lodun 2011. Awon agbaagba ile Yoruba ni won pe mi pea won fe ki n tun aarin awon Yoruba se nipinle Ogun. Ni bayii, mo ti n ronu lati fa a le awon Ijebu lowo, nitori pe bi Ijebu ba se e, Egba lo kan. Ojogbon Adedeji lati United Nations ti se e rii.

AWIKONKO: Gege bi alaga Igbimo Agba Yoruba nipinle Ogun, kinni in egbe yi da le lori, ati pe ki nidii ti won fi da a sile?
OMONAYAJO: Nnkan ti Igbimo Agba Yoruba duro le lori naa ni won fi da a sile, a ko fe ki iya je omo Yoruba kankan, a si tun fe e ko awon omo Yoruba nipa iwa omoluabi, ka fowosowopo, ka si le nilosiwaju, nitori pe agbajowo la fi n soya. Koko to wa nibe ni pe a ko gbodo pa iwa omoluabi wa tii, iyen nip e ka feran enikeni wa, ka si tun se otito pelu iwa to dara. A n kede pe kawon omo kekeeke ni ibowo fagba atawon asiwaju, nitori pe Olorun gan an so pe ka bowo fawon alase,nitori pe oun loun fi won sibe. 

AWIKONKO: Ki lawon aseyori yin laarin asiko yii?
OMONAYAJO: Mo ti se opolopo awon aseyori. A ti se awon kan ti Olorun ti fun wa se, a ti se awon kan ti a ko tii pari, a si tun n se awon kan lowo. Nile Yoruba, isoro ta a ni ni pe gbogbo eeyan lo fe e je olori, kii sii se gbogbo eeyan ni Olorun da lati se olori. Eni kan soso lo le je olori kawon toku le gbaruku tii. A ti wa atunse si opolopo ede-aiyede to n sele nile Yoruba, awon omo wa ti won nisoro la ti sise lori e. A ti jokoo lori awon igbese to ye ka gbe lori awon omo wa to kawe gboye, sugbon ti won ko rise se. Bi a ba ni ka woo, gbogbo nnkan ko le se e se tan lojo kan soso, die-die ni, sugbon ebe la n be ijoba ki won le ba wa gbe ise jade fun won.

AWIKONKO: Ki ni ajosepo egbe yi pelu egbe Afenifere?
OMONAYAJO: Bi e ba wo egbe Afenifere nigba kan, e maa sakiyesi pe o pin sona meta abi merin, sugbon ti ko sele laarin Igbimo Agba Yoruba, eyokan soso ni wa. Eekeji nip e, oselu ni won fi da egbe Afenifere sile, a ko fi oselu pile egbe Igbimo Agba Yoruba. A wa ko so pe keeyan ma se oselu, sugbon to ba de inu Igbimo Agba Yoruba, o ni lati gbe oselu segbe kan, o si gbodo fowosowopo peluu wa. Nitori atunse ati atunto la fi da egbe Igbimo Agba Yoruba sile, eni to ba si darapo mo wa gbodo je eni to n fe atunse laarin gbogbo awon oloselu. Omo iya kan soso ni wa, a ko si gbodo maa ja.

AWIKONKO: Ipinle meloo lo n se egbe yii?
OMONAYAJO: Ipinle mewaa lo n se egbe Igbimo Agba Yoruba, awon naa ni Eko, Ogun, Oyo, Osun, Ekiti, Ondo, Kwara, Edo ati Delta nitori pe omo Oduduwa ni gbogbo wa. Ajosepo to dan monran lo wa laarin wa. Ipinle kookan lo ni ileese egbe, a si tun ni olu-ileese to so wa po. Yato si eyii, a tun ni eka sawon ilu Oyinbo kaakiri, bii Britain, Canada, Uk, US ati bee-bee-lo.

AWIKONKO: Kinni ojuse egbe yi ninu eto isejoba orileede yi, paapaa lawon ipinle ti e ni eka sii, ati pe ki ni ajosepo egbe yi peluu egbe Oodua Peoples’ Congress (OPC) ti Aare Gani Adams da sile?
OMONAYAJO: Egbe OPC ti Aare Gani Adams da sile je gege bi eka ninu egbe Igbimo Agba Yoruba. Won duro gege bi egbe eleto aabo fun omo Yoruba, bo tile je pe awa ko jagun mo, a ko si gbadura fun ogun. A ko fe ki ijoba ri wa gege bi egbe alatako, tabi egbe to n bu enu ate lu ijoba, nitori pe ilosiwaju la n wa. Alaafia ile Yoruba, paapaa orileede Naijiria la n wa. Yoruba kii fi ada ati ibon ja, opolopo la maa n lo lati fi ja fun eto wa. Ko digba ta a ba bere sii pariwo kaakiri, tabi fa wahala, ki won too le mo pe inu n bi wa. Bi e ba wo asiko ogun Biafra, e maa sakiyesi pe Yoruba ko yo ibon tabi ada, opolo wa la fi yanju ogun naa. Ti e bar anti nigba naa, Oloogbe Obafemi Awolowo soro nigba naa pe a le awon ota wa, a tun n fun won lounje, o rii pe ounje ti won fun won yen lo pana ogun, kii se iye ota ibon. Ogbon la fi n se ohungbogbo ta n se.

AWIKONKO: Awon wo ni won n se egbe Igbimo Agba Yoruba, ati pe awon wo lo le darapo mo egbe Igbimo Agba Yoruba?
OMONAYAJO: a ti se atunse iwe ofin (constitution) wa. Eni to ba je okunrin, o ni lati je omo ogota odun, ta a si rii pe o ni laakaaye, o si gbogbo faramo gbogbo ilosiwaju ta a n wa, iru eni bee le darapo mo wa. O maa foruko sile, aa si san owo iforuko sile, ka too le gba a wole. To ba je obinrin, o gbodo ti pe aadota odun. Awon to ba fe e darapo mo wa gbodo rii pe oun setan lati maa se gbogbo eto e to ba ti n to asiko. Kii se tipatipa la fi n gbaayan wole, eni to ba fe e darapo gan an, a ni lati wo iru eni to je. 

AWIKONKO: Amoran yin fawon omo Yoruba, paapaa ijoba orileede Naijiria?
OMONAYAJO: Irepo ati ododo ni maa fi ranse sawon omo Yoruba, paapaa awon omo Naijiria pelu ara won. Ki won ma se imotara-eni nikan, nitori pe ibi ti otito ati ife ni Olorun n wa. Amoran mi fun ijoba ni pe ki won se daadaa, ki won si ranti pe won maa kuro nibe to ba di ola, nitori pe ohun teeyan ba se lonii n bo wa di itan. Ki won faaye sile fawon odo naa lati di awon ipo kan to to si won mu, nitori pe pupo ninu won lo logbon lori, ti won si ni agbekale ti won lati mu idagbasoke ba orileede, ati pe nitori pe won ko mo eeyan to wa nipo ni won ko se ri ipo di mu ninu eto isejoba. A fi ki ijoba tete wa ona lati da ise sile fawon omo to n kekoo jade yii, tabi ki won wa ona ti owo fi ma maa wole sapo awon omo yii nitori pe owo ni won a fi maa se nnkan ti won ba fe e se.  ko si nnkan to buru ninu ki ijoba fawon odo laaye lati sejoba, nitori pe won ni omode gbon, agba gbon ni won fi da Ile-Ife.

AWIKONKO: Nje e nigbagbo pelu asiko olaju ta a wa lonii pe ayipada tun le de ba Asa ati Ise Yoruba?
OMONAYAJO: Pelu awon nnkan temi n ri nipinle Ogun, ayipada ti de ba asa Yoruba, bi e ba ri Komisana foro Asa ati Isese nipinle Ogun, iyen Basorun Muyiwa Oladipo bo se n se bebe nipa gbigbe Asa Yoruba laruge. A ko si le ki oun nikan lai ki eni to fi sibe, iyen Gomina Ibikunle Amosun. A tun n rowo Ojogbon Wole Soyinka naa nipa Asa. Awa gan gan la ko ni faaye sile pe ko pare, nitori naa bi won ba ti pe wa sii, a fi ka sunmo won. Asa wa ti n pada si ti tele, nnkan to ku ni pe kawon omode bowo fawon agba won. Igbimo Agba Yoruba ta n so pe a n se yii, awon Oba alade gan an lo ye ko je Igbimo Agba Yoruba, oludamonran lo ye ki awa je, sugbon nitori pe ijoba lo n dari awon Oba, o niwonba ta a le pe awon Oba sii, bo tile je pe aaye wa lati maa gbamonran lodo won, ki ilosiwaju ba a le maa po si.

PÍN-IN KÁÀKIRI