PUPO NINU AWON OLOSELU NI KO FERAN MEKUNU - IMALIAN BOY - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 6, 2018

PUPO NINU AWON OLOSELU NI KO FERAN MEKUNU - IMALIAN BOY

Bowale Adesegun

Odu ni Alaaji Gbenga Adebayo Oladunni topo awon eeyan mo si Imalian Boy. Bo se je gbajumo sorosoro, bee naa lo tun je ilu-mon-ka ati ogbontarigi nidi ise tiata, bee lo tun je enikan tawon eeyan n wo gege bi awokose.


Lojo Fraide to koja yi ni Alaaji Gbenga Oladunni b'AWIKONKO soro lori ipinu e lati jade dupo aga nile igbimo asofin ipinle Ogun lati ekun, Ariwa Abeokuta labe egbe oselu Accord.

Imalian Boy tawon kan tun n pe ni Imalian Man bayii ti figba kan ri jade dupo yi sugbon to padanu sowo alatako e, iyen lodun 2015.

Nigba to n soro, O ni "Kii se akoko re e ti mo ti n dupo yi, nitori pe mo si ni nnkan ti mo fe e se fawon araalu ni lo je ki n tun fe e pada dije. Awon to wa nibe gbiyanju nnkan ti won le se, sugbon bi e ba woo, awon oloselu yi ko feran awon araalu dokan.

"Lara nnkan ti mo fe e se ni pe, ma a bawon egbe mi soro lati se ofin to maa ro awon araalu lorun, nitori pe bi ofin to ro awon araalu lorun ba wa, opin ti de ba gbogbo wahala ati idaamu won.

"Bi a ba se ofin pe ki ounje po niluu, inu awon agbe yoo dun, awon to wa nigberiko naa yoo bo sinu ayo. Oja ti won maa gbe wa fawon eeyan ko nii han ju bo se ye lo, ta a si maa rii pe ounje repete wonu ilu wa.

Nigba to n soro lori bo se fe e gba egbe oselu Accord jade, Oladunni so pe iwa omoluabi ti won fi pile egbe naa lo je koun darapo mo won, ati pe eto ati ilana ti won sagbekale e lo tun fokan oun bale, nitori pe nnkan to n je awon araalu niya gan an lo wa ninu agbekale won.

Bakan naa ni ti igbaradi e, o ni bo tile je pe ki egbe too fa oun kale loun ti n gbiyanju agbara oun, sugbon ni bayii, o ti wa a di iduro ko si, bee ni ibere ko si, toun yoo lo gbogbo ijoba ibile to wa l'Ariwa Abeokuta ki idibo too waye.

Siwaju sii, Imalian Man so pe oun nigbagbo ninu ajo eleto idibo, INEC pe won yoo se bo ti to ati bo ti ye ninu idibo to n bo lodun 2019.

Lafikun, o gbawon araalu lamonran pe ki won ma se ti oro owo ki won too dibo, nitori pe bi won ba wo ti owo ni, won ko nii dibo fenikeni, ati pe bi eni to ta ojo iwaju e loro eni to gba owo lowo oloselu ko too dibo rii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI