Soosi
Ori Oke Ina ati Ise Iyanu (Mountain of Fire and Miracles Ministry), MFM ti kede
sita pe oun yoo sayeye nla lati fi dawon obinrin soosi naa l'ola.
Alakoso
ekun soosi naa, ti Guusu/Iwo-Oorun (Southwest Region 1 Headquarters), Pasito
Owolabi Ayodeji lo kede lasiko to n se ifilo, ko too bere iwaasu lojo Sande to
koja yi, iyen ana.
O ni o
pon dandan lati da awon obinrin lola, ati pe iru e ko sele rii, akoko re e,
tawon si gbodo je ko larinrin, nitori pe orisirisi awon alejo kaakiri eka soosi
naa lawon yoo pe lati wa a bu ola fun won.
Ose
keta ninu osu kokanla odun yi (3rd week in November) ni ayeye naa ti won pe ni
Ipago Awon Obinrin Iberepepe, (Women Foundation Convention) yoo waye.
Pasito
Owolabi tenu mon on pe asiko re e lati sayeye fawon obinrin, paapaa bi won se maa
n so pe okunrin to ba n se aseyori laye, latari atileyin iyawo e ni, idi tawon
fee fi mo riri ipa ribiribi tawon obinrin soosi naa n ko.
O tun
so pe alakoso awon obinrin ni olu-iya soosi naa lati ilu Eko yoo wa nibi ipago
naa, to fi mo awon iyawo awon Alakoso ekun kookan to wa niluu Abeokuta ati
agbegbe e ni won ti fiwe pe.
Bakan
naa lo rawo ebe sawon eeyan lati da si eto ayeye naa nipa fifi owo atawon ebun
lorisirisi ran won lowo, lati rii pe ayeye naa dun koja eto tawon ti la kale.
Bee lo
tun so pe kawon to ba fe e ran won lowo, paapaa awon to ti seleri fun won tete
mu awon nnkan ti won ba fe e ri ran won lowo sile laarin asiko yi si ipari osu.
Ninu
iroyin min in to fara pe e ni Pasito Owolabi tun ti kede pe ojo kokanlelogun
osu yi (October 21) ni ipago lati sayeye fawon eya Igbo to wa ninu soosi naa
yoo waye, ati pe won fe e fi eka Igbo lole naa pelu lojo naa.