IDIBO PAMARI: EGBE OSELU ADP FA DIMEJI BANKOLE KALE GEGE BI ADIJE SIPO GOMINA LODUN 2019 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 8, 2018

IDIBO PAMARI: EGBE OSELU ADP FA DIMEJI BANKOLE KALE GEGE BI ADIJE SIPO GOMINA LODUN 2019

Bo tile je pe latigba ti won ti da egbe oselu Action Democratic Party, ADP sile lorileede Naijiria ni nnkan bi odun marun seyin lawon eeyan ti n so pe olori ile igbimo asofin teleri lorileede yi, Onarebu Dimeji Bankole ni won yoo lo lati dije dupo gomina lodun 2019.

Ko si nnkan meji to mu kawon eeyan maa gbe oro yi kaakiri, bi ko se ti bi baba okunrin naa, Oloye Suarau Alani Bankole se je alaga igbimo apase (BoT Chairman) egbe naa.

Lopin ose to koja yi, iyen lojo Satide Abameta lawon igbimo amusese (NWC) tegbe naa ran wa sabojuto eto idibo abele, iyen pamari kede pe Onarebu Dimeji Bankole lo jawe olubori lai ni alatako.

Oloye Ambasado Chamberlain Amadi lo kede oro naa ni ileese egbe to wa ladugbo Onikolobo niluu Abeokuta. Nibe lo ti je ko di mi mo pe eto idibo pamari naa lo gege bo se ye lai ni awuruju ninu.

Amadi so pe bi won se dibo pamari fun gomina naa ni won dibo fawon oludije sawon ipo to ku bii seneto, asoju-sofin ati omo ile igbimo asofin.

O ni kaakiri woodu igba ati merindinlogoji (236) ni eto idibo naa ti waye, to si je pe ninu awon 157,600 to foruko sile lati dibo, awon 157,466 lawon to dibo fun Dimeji Bankole.

Omoba Kunle Olateru Olagbayi to tele Oloye Amadi ninu oro ti e so pe latari asiko lawon ko se nii ka oruko awon adije sawon ipo to ku sita, sugbon tawon yoo le awon oruko naa lai pe.

Nigba toun naa n soro, alaga egbe oselu naa nipinle Ogun, Oloye Wale Egunleti dupe lowo awon NWC ti won wa, bee lo je ko di mi mo pe ipolongo idibo kaakiri awon ekun ati gbogbo ijoba ibile to wa nipinle Ogun lawon yoo tun lo lati bawon eeyan soro.

PÍN-IN KÁÀKIRI