Latari
iroyin to gba ori ero ayelujara nipa ti ile olowo nla ti gbajumo osere tiata
nni, Mercy Aigbe Gentry sese ra, tawon kan si n so pe kii se ise owo e lo fi ra
a, bi ko se pe baba alaye kan ti Mercy n te lorun daadaa lo fi ta a lore.
Won ni
baba alaye naa to tun je okan lara awon gomina lorileede Naijiria lo fi owo ilu
ra ile naa fun Mercy to je iya olomo meji, ti ko si tun si nile oko e lasiko
yii.
Mercy
Aigbe ti wa a soko oro sawon to n gbe iroyin naa kaakiri, pe ori elegan lo
baje, nitori naa kawon abinu oun lo o wa ibi kan jokoo sii, nitori pe kekere ni
won si ri, eyi to ju iyen lo si n bo.
Ilu
mon on ka osere tiata tawon eeyan n gba ti e gidi gan an lasiko yi je ko ye
awon to n gbe aheso naa kaakiri pe ise aseku-dorogbo toun n se lo pese owo toun
fi ra ile naa, ko da a, ti soobu itaja olowo nla naa tun n bo lai pe.
Fawon
ti ko ba mo, gbajumo oniroyin ori ayelujara kan (Blogger), iyen Stella
Dimokokorkus lo koko gbe iroyin naa jade sita, bo si ti se jade lawon eeyan ti
bere sii gbe e kaakiri, tawon kan si n bu enu ate Mercy, paapaa tawon kan tun n
so pe obinrin naa ti so ise tiata di ise asewo.
Ninu
oro ti Mercy Aigbe fi dahun lo ti so pe "Ko seni to ri bi mo se n sise
doru pelu fiimu yiya! Bi mo se n kopa wakati merinlelogun, ko seni to ri mi
nigba ti mo n wa lori itage niseju-iseju. Ko seni to ri awon igba ti mo n gbe
oja sori kiri niluu London, LA, New York, Turkey, Vietnam atawon min in. Ko
seni to ri awon awoodu, pelu bawon ileese olowo nla se yan mi gege bi asoju
won.
"Fun
bi odun meedogun gege bi osere tiata, mo ra ile, won wa rii bi nnkan Barbara!
Won fe e maa daruko awon okunrin oloro ti won mo pe awon lo wa nidi aseyori mi,
nitori won ko lero pe obinrin pe obinrin le se iru aseyori nla bee.
"E
ni lati duro digba ti maa si ile itaja (Complex) mi, nigba yen, boya se le maa
kuku gbe majele je lori oro mi. Mo sese n bere ni."
Die re
e ninu oro ti Mercy Aigbe ko ranse sawon to n gbe ayederu iroyin kaakiri nipa
bo se n tayo laarin awon elegbe e nidi ise tiata to yan laayo.