NITORI DAPO ABIODUN, WON NI AMOSUN FE E FI EGBE OSELU APC SILE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 12, 2018

NITORI DAPO ABIODUN, WON NI AMOSUN FE E FI EGBE OSELU APC SILE


Bi iroyin to n lo n lo kaakiri igboro ipinle Ogun, paapaa orileede Naijiria lasiko yi nipa pe gomina Ibikunle Amosun fe e fi egbe oselu APC sile lo sinu egbe oselu min in, a je pe afaimo ki egbe oselu APC naa ma pada tuka.

Fawon to ba mo bi oselu ipinle Ogun se n lo si, paapaa ninu egbe oselu APC, won a mo pe ko si nnkan meji to n da wahala sile bi ko se ti idibo pamari sipo gomina to waye lai pe yi, ti won ni Dapo Abiodun lo wole, eni ti Gomina Amosun ko figba kan gba ti e.

Onarebu AbdulKabir Adekunle Akinlade ni Gomina Amosun fa kale lati gbe ijoba fun, sugbon ti won ni awon kan ko faramo, ati pe won ni se ni Gomina Amosun n da ase egbe oselu naa pa.

Lojo Monde ose to koja yi ni Gomina Amosun ti leri nita gbangba pe oun yoo fi gbogbo nnkan toun ni bawon alatako oun ninu egbe naa ja, nitori pe orisirisi iro ni won ti loo pa moun lodo Aare Muhammadu Buhari niluu Abuja.

Ni bayii, a gbo pe nibi ipade ti Gomina se pelu awon omo egbe to je ti e lo ti je ko ye won pe bi igbimo amusese NWC egbe naa ba ko lati fi oruko Adekunle Akinlade toun fe dipo oruko Dapo Abiodun ti won ko, se loun yoo kuku fegbe naa sile fun won.

Bawon kan se n so pe egbe oselu Accord ni Amosun n gbero lati lo, bee lawon kan n so pe egbe oselu Accord ko le faaye gba a lati wa a dabaru eto ati ilana egbe won.

Bi nnkan ba se n lo l'AWIKONKO yoo mu wa fun un yin lati mo. Ekunrere n bo lai pe.

PÍN-IN KÁÀKIRI