WON NI OBASANJO KO DEEDE DARIJI ATIKU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 13, 2018

WON NI OBASANJO KO DEEDE DARIJI ATIKU O

Ko seni to ri awon agbaagba Wolii Olorun ti won gbe Atiku leyin lo ka Obasanjo mole loni-in ti won ko maa so pe, dajudaju, ibo 2019 yii yoo le koko fun Buhari.
 
Awon ojise Olorun ti Alhaji Atiku Abubakar be lowe si Oloye Olusegun Obasanjo niwonyi; Wolii Bishop Oyedepo to ni ijo Winners, Bisoobu ijo Catholic Diocese ilu Sokoto, Mathew Kukah, Afaa agba, Sheik Ahmed Gumi, bee lawon agbaagba egbe PDP, paapaa alaga won, Omooba Uche Secondus, Ben Murray Bruce atawon alenu-loro mi-in ninu egbe oselu ni won jo wa nibe.
 
Ohun kan ti won lo se nile Obasanjo niluu Abeokuta loni-in; ko ju bi won yoo se ri ojuure baba naa fun Atiku Abubakar, ki o le ba jawe olubori ninu ibo aare to n bo lodun 2019.  
 
Deede aago kan osan koja die ni won de ile Obasanjo, ko si pe sigba naa ni Bisoobu Oyedepo darapo mo won, nni won ba tilekun mori lati sapade bi ibo odun to n bo yoo se senuure fun Atiku, eni to se igbakeji Obasanjo laarin odun 1999 si 2007.

EKUNRERE OHUN TI OBASANJO SO NIYI
Ni tododo, lodun naa nigba ta a bere, erongba wa ni pe Atiku ni yoo bo sipo aare orile-ede yii ni kete ti mo ba ti gbe ijoba kale. 
 
Niwaju awon eni iyi yii, mo setan lati so asiri nla kan. Ki n ma tan yin, mo ti sayewo ona ti Atiku gba fi kuna, mo si ti ri i pe okunrin yii ti yipada, o ti di atunbi, bee oju ona to ye fun omoluabi lo n to bayii.
 
Gege bi mo ti se so o lopo igba seyin, ki i se pe ohun to se fun mi lo n dun mi, bikose awon iwa to hu nigba yen si egbe wa, ati eyi to hu si ijoba atawon eeyan orile-ede yii; iyen gan-an lo bi mi ninu. Ohun to se fun mi ko lo dun mi gan-an to bee.
 
Igbese mi nigba yen mo gbe e latari awon iwa kan ti iwo naa hu nigba yen, ohun ti mo si se, mo nigbagbo wi pe fun ilosiwaju gbogbo eeyan orile-ede yii ni.
 
Sugbon ni bayii, lenu wakati meloo kan ti a ti jo wa nibi, mo ti ri Atiku to yato patapata si bo ti se ri tele, mo si mo daju pe o ti di atunbi patapata, ati pe aforiji to wa toro lodo mi loni-in, ohun to wa se tokantokan ni, bee lo han daju wi pe o satan lati satunse lawon ibi kan to ku si.

Ni bayii, mo fe fi da o loju wi pe gbogbo ese yoowu ti o se mi pata, gege bi onigbagbo ododo to n toro aforiji ese lowo Olorun, to si n wa iyonu Oluwa pelu, mo ti foriji e tokantokan. Bee gege ni mo fe ki o kekoo gidi latara awon ohun to ti se seyin to ku die kaato, mo si nigbagbo yoo dara fun e.
 
Ohun kan ti mo mo daju ni pe, niwon igba ti o wa ojuure egbe, eyi to fun e lanfaani loni-in lati fe dije-dupo aare, imoran mi fun e ni pe, gbiyanju lati fa awon ti e jo dije dupo yii ninu egbe mora, ki erongba re le wa si imuse.
 
Mo nigbagbo wi pe irufe emi irele to gbe e de odo mi loni-in yii, irufe okan bee yoo ran o lowo lati fi bori awon ibomi-in to ye ki o mojuto, paapaa bi o tun se ko awon eeyan iyi wa sodo mi;  mo nigbagbo pe igbese yii yoo wulo fun o gidigidi lati fi yanju awon ibi yooku to ba ye ki o mojuto yala ni orile-ede yii tabi loke okun.
 
Bakan naa ni mo fe fi da e loju wi pe ni gbogbo ona ti o ba ti nilo iranlowo mi, mo setan lati se e fun o; ni gbogbo ojo tabi igbakuugba.
 
Ti a ba n so nipa isakoso ilu, ohun to daju ni pe, Atiku ni imo kikun nipa eto oro aje ju eni to wa lori ipo aare lasiko yii lo, eyi ti mo nigbagbo wi pe, wa a lo lati fi pese ise fun irorun araalu.
 
Owoja tie kale, koda o ka oko paapaa, bi o ti se gbajumo ni Nigeria nibi, bee gan-an loro e se ri ti a ba n so nipa ki eeyan lawon eeyan to le ba dowpo lawon ile okeere.
 
Eeyan kan ti awon eeyan a le foro lo, ti a le gbamoran, irufe eeyan bee ni Atiku, mo si nigbagbo wi pe, iwa yii niwo tun fi dara ju eni to wa nipo aare lasiko yii lo. 
 
Abajo ti Pasito Tunde Bakare fi sapejuwe re gege bi oloselu nla kan ti yoo je itewogba fun gbogbo eya orile-ede yii. Mo si nigbagbo wi pe, wa gbiyanju lati mojuto awon oro ati isesi eleyameya to le koba orile-ede yii.
Mo fe ki o ranti wi pe nibi ti o ti ba ara e loni-in, pupo ninu awon agbaagba egbe ni won sise takuntakun ti o fi ri aaye debe, bee gege lawon mi-in naa se e ko le bo si i fun e. Fun idi eyi, mo n fi asiko yii ba o dupe lowo gbogbo won, ki Olorun tubo ba mi se ona won nirorun.
 
Nigba ti o ba di Aare orile-ede yii pelu Ogo Olorun, eyi ti mo nigbagbo wi pe wa de ipo ohun. Mo fe ki o ranti awon ise takuntakun ti a jo se lasiko ta a wa nijoba, mo fe ki o ranti wi pe, eto ijoba ti a se nigba yen, ojulowo  ijoba to wa fun gbogbo omo Nigeria ni, nibi ti a ko ti fi eto dun enikankan, ti ohun to ba to si kaluku n bo si i lowo laisi iwa eleyameya kankan. 
 
Bo tile je pe opo ojo lo ti ro, sibe mo nigbagbo wi pe wa lo ipo re pelu otito ati jije omoluabi, bee lo gbodo gbogun ti iwa ajebanu, ki o si ri i daju pe awon onisunmomi, oro won di afiseyin ti eegun n fi aso.
 
Sa o, kin ni kan ni mo fe bi o loni-in, ti mo si fe ki o seleri niwaju Olorun Alaaye atawon eeyan to wa nibi ni pe, nje o setan lati tele ofin orile-ede yii, ati pe se o setan lati ri Nigeria yii, gege bi okansoso ni, ti o ko ni i sagabangebe laarin awon eya yooku.
 
Ranti wi pe ohun to le mu idagbasoke ba orile-ede yii ni eto oro aje to n se daadaa atawon ohun amayederun. Bee ni mo fe ki o ranti awon obinrin ninu ijoba re, ki o si gba awon odo laaye pelu.
 
Bakan naa ni mo n fi asiko yii ke si gbogbo awon alase ti oro kan lori imurasile fun eto idibo, mo fe ki won ri i daju wi pe eto idibo to muna doko ni won seto e, ti ko ni i ni konu-n-koho kankan ninu rara.
Leekan si i, mo ki o ku oriire, bakan naa ni mo dupe lowo eyin ojogbon ti e je ki ipade yii waye.
 
Mo setan lati fokan tan yin, bee ni mo nigbagbo wi pe, e ko ni i kuna lati maa gba awon eeyan wa niyanju; eyi ti yoo mu ilosiwaju rere ba orile-ede yii, ti yoo fi depo giga ti Olorun ko mo on, ti yoo si wa nibi giga alailegbe.

PÍN-IN KÁÀKIRI