ÀRÀGBÉ LAYÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 10, 2018

ÀRÀGBÉ LAYÉ

Ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó rí ni tó mọ́jú, àwọn kan ni kò ti ẹ wo ibi ti a wa. Mo n fi àsìkò yi dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ ẹ̀yin olólùfẹ́ wa, pàápàá ẹ̀yin olólùfẹ́ èmi ọmọ yín fún àdúrótì yín. Ẹ̀yin gan an ni èjìká tí kò jẹ́ kí aṣọ kó yẹ̀ lọrùn mi.


Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé ọ̀kan kò j'ọ̀kan làwọn àkọ́lé tí a máa n mu wa fún ùn yin l'ọ́sẹ̀-ọ̀sẹ̀, èyí tí a má fi n gba ara wa niyanju l'abala oro sunnukun yi, ti é sí mo pe toni ko jọ tana la ma fi n ṣe e.

Nínú ètò kan tí mo ń gbọ́ lórí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì (rédíò) ni atọ́kùn ètò náà tí mẹ́nu bá gbólóhùn yìí.

Atọ́kùn eto naa ṣe àlàyé nípa ohun tí gbólóhùn náà túmọ̀ sí. Lára àlàyé tó ṣe ni pé ilé ayé kéré jọjọ nínú lẹ́tà àkọsílẹ̀, torí kò ju ẹyọ ọ̀rọ̀ mẹta lọ. 

Àmọ́ ìtumọ̀ rẹ kẹnu ju ohun tí ẹ̀dá lérò lọ. Ó tesiwaju pé láti kékeré ni òun ti máa ń gbọ́ gbólóhùn náà pé ÀRÀGBÉ LAYÉ.

Àmọ́ láti ìgbà náà òun kò tíì rí olówó ayé kan tó ra ilé ayé gbé rí. Ó tún sọ pé àwọn mìíràn a máa sọ pé abẹgbe láyé. Síbẹ̀ òun kò rí ẹri aridaju wípé ọ̀rọ̀ náà jẹ́ òótọ́.

Mi o gbọ́ eto naa tán tí mo fí wọ oko ìrònú lọ. Tí mo sì mú gege mi láti kọ àpilẹ̀kọ yìí. Kii ṣe pé mo ń kọ àpilẹ̀kọ yìí láti tako èrò atọ́kùn eto naa. Àmọ́ ńṣe ni mo ń kọ àpilẹ̀kọ yìí láti ṣe àlàyé ohun tí gbólóhùn èdè yorùbá náà túmọ̀ sí pé ÀRÀGBÉ LAYÉ.

Gbogbo èèyàn ló ní àǹfààní láti sọ èròngbà rẹ lórí ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ rẹ bá ṣe rọ̀ mọn ọn.

Ọjọ́ tí pẹ tí mo ti máa ń ronú lórí koko ọ̀rọ̀ yìí pé ṣe ó le jẹ òótọ́ ṣá. Àbí owó kí ni ẹ̀dá lè ní lọ́wọ́ tí yóò fi ra ilé ayé gbé. Eelo ló lè máa bẹ lọ́wọ́ ọmọ ènìyàn tí yóò wá ká ayé lódindi? Bí a bá sì tún sọ pé abẹgbe láyè. Ta la o pé kò wá lọ bá wà bẹ ayé?

Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrònú mo wà rí í pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ pé èèyàn lè rà ilé ayé. Àmọ́ láti ra ilé ayé gbé kò là owó lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ipo ohun dúkìá ó lè rà ayé gbé. Torí àwọn àgbà bọ wọn sọ pé: Níní ọlá ogun ni, afaini wàhálà. Bẹ́ẹ̀ ni gbingbiniki òògùn ó lè rà ayé gbé. Ṣé èwe a kúkú máa sunko nígbà mìíràn.

Báwo lao wá ti rà ilé ayé gbé báyìí?? Mọọ gùn, mọọ tẹ ẹ̀dá nínú ayé, báwo ni yóò ti gùn iyán ewùrà tí kò ní lẹmọ?? Lati ra ilé ayé gbé kò nira. Kódà ohun tó rọrùn julọ nígbèésí ayé nìyẹn. Àmọ́ ọpọ èèyàn ni kò mọ èyí. Èyí ló sì mú kí ẹlòmíràn máa sáré mọto kọ lu kẹkẹ.

Láti ra ilé ayé gbé ohùn kan ṣoṣo ni ẹ̀dá nílò tí yóò san. Ohun náà o sì nira láti ni. Ìwà ni ẹ̀dá fi ń rà ilé ayé gbé. Bí ẹ̀dá bá ní ìwà ire. Bí èèyàn bá yá ọmọlúwàbí láwùjọ. Gbogbo èèyàn ni yóò fẹ́ràn rẹ. Ìwà lọba fi ń rà ìlú gbé kó le pẹ lórí apere àwọn bàba nlá rẹ̀. Bí ọmọbìnrin ó bá n'íwà kò lè rà ilé ọkọ gbé. Bí èèyàn kò bá níwà àtàtà ṣe ni yóò máa wà ọ̀tá fún ara rẹ.

Ìwà ire kò pé kí abinu ẹni má ṣe di ẹ̀dá sínú. Àmọ́ yóò ṣọwọn láti rí ẹ̀dá tí yóò máa bá ẹni níwà ọmọlúwàbí bínú.

Aragbe láyé ni tòótọ́. Ẹ jẹ ki kaluku wá lọ tún ìwà ara wa ṣe láti ra ilé ayé gbé fún ara wa àtàwọn ọmọ tao fi sílẹ̀ sáyé nígbà tá bá jáde láyé.


AREMO JAH
#onkorin
#onkotan
#akewi
+2348170981831

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI