AWON AGUNBANIRO NI WON TUN N JI GBE BAYI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 15, 2018

AWON AGUNBANIRO NI WON TUN N JI GBE BAYI O

Bi kii ba a se pe awon olopaa orileede Naijiria ko sun asunpara ni, ati pe won kii fi oro aabo emi ati dukia sere mo lasiko, o see se kawon agbenipa ti won ji awon odomokunrin ati odomobinrin marun kan ti won sese pari ileewe giga tan, ti won si n lo sin orileede Baba won lose meta seyin.

 

Gege ba a se gbo, lati ipinle Oyo la gbo pe awon agunbaniro marun naa ti won pe oruko won ni; Abiola Temitope, Olubisi Adekanmi, Jose Temitayo, Folarin Opeyemi ati Shonibare Ademola ti kuro, ti won si n lo sipinle Rivers ati Akwa-Ibom.

Opopona Oweri si Port-Harcourt, iyen lagbegbe ijoba ibile Ohaji/Egbema nipinle Imo la gbo pe awon agbenipa yi da moto won duro, bi won si se ri aso agunbaniro lara won ni won ti pe won bole, ti won si fe e gbe won wonu igbo lo, lati loo pa won soogun owo.

Opelope awon olopaa ta a gbo pe asiko ti won n ko won lo sibi ti won ti fe e pa won lasiri won tu, ti won si ri awon agunbaniro maraarun yi gba pada.

PÍN-IN KÁÀKIRI