AWON OLOPAA N WA AWON OBI OMO TI WON JI GBE YI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 14, 2018

AWON OLOPAA N WA AWON OBI OMO TI WON JI GBE YI O

Bo tile je pe a ko tii le fidi e mule boya awon olopaa ipinle Ekiti ti ri awon obi omodebinrin omodun mejila kan, Tawa Taiwo ti won lawon agbenipa ji gbe, sugbon ti won ko ri lo, to mu ki won tii danu sinu igbo.

 

Ilu Ilorin ni won ti ji Tawa gbe, sugbon ta a gbo pe ilu Ayede-Ekiti nipinle Ekiti ni won ti rii, to n rin kaakiri adugbo ti ko mo lojo Monde ijeta.

Awon eleyinju aanu kan la gbo pe won ri Tawa nibi to ti n rin kaakiri egbe titi, ti won si da a duro lati beere orisirisi ibeere lowo, toun naa si salaye bo se rin irin fun won.

Leyin e la gbo pe won gbe e lo tesan olopaa lati tesiwaju iwadii lori e, ki won si muu lo sodo awon obi e.

Awon olopaa yi la gbo pe won gbe Tawa lo si eka ileese ijoba, iyen Ministry of Women Affairs and Social Development lati gba ise naa se gege bi ise won.

Titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan la ko tii gbo boya won ti mu omo naa lo sodo awon obi e,  sugbon ta a gbo pe iwadi si n lo lowo.

PÍN-IN KÁÀKIRI