BISOOBU OYEDEPO LE PASITO E TO FERAN JU DANU NITORI IWA AGBERE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 17, 2018

BISOOBU OYEDEPO LE PASITO E TO FERAN JU DANU NITORI IWA AGBERE

Iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi ti je ko ye wa pe igbimo ti Oludasile soosi Winners Chapel, Bisoobu Oyedepo gbe dide lati sewadi okan lara awon Pasito soosi ti won fesun agbere kan ti pari iwadi won, won si ti pase pe ki won le Pasito naa, Dokita Olumiyiwa Oludayo danu.


Dokita Oludayo la gbo pe o je okan lara awon Pasito ti Bisoobu Oyedepo feran ju, oun si ni oluforokusile (Fmr. Registrar) ileewe ti soosi naa da sile, iyen Covenant University.

Yato si esun agbere ti won fi kan okunrin naa, orisirisi iwa ibaje lo tun je jade leyin iwadi tawon igbimo naa se.


Lesekese ti asiri si ti tu sita ni Bissobu Oyedepo ti ni won da okunrin naa duro, ati pe ki won tun le e danu nitori pe se lo fe e ba oruko soosi naa je, tawon ko si nii gba.


PÍN-IN KÁÀKIRI