DAPO ABIODUN KO AWON AGBAAGBA LOO BE AMOSUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 17, 2018

DAPO ABIODUN KO AWON AGBAAGBA LOO BE AMOSUN

ABIMBOLA ABERUAGBA

...L'AMOSUN BA LOUN KO NII GBA


Bi oryin to te AWIKONKO lowo lai pe yi ba fi le je otito, a je pe Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun ko tii setan lati je ki wahala to n fojoojumo pin egbe oselu APC nipinle niya pare, ati pe bii igba to fe e je gaba lori gbogbo awon omo ipinle Ogun patapata loro e fe e ri.

Lojo Fraide ana, la gbo pe Omoba Dapo Abiodun ti won loun lo jawe olubori nibi idibo gomina abele ti won koja lo gbe awon agbaagba egbe oselu naa ti won gba ti e lo sodo agba oloselu nni, Oloye Olusegun Osoba niluu Abeokuta pe ki won ba oun be Gomina Amosun lati je koun gbegba oroke nibi idibo gomina to n bo lodun 2019.

Be o ba gbagbe, idibo pamari naa lo pin egbe oselu APC nipinle Ogun si eleyemeya, ti ko fi seni to gba ti ara won mo, bawon kan se faramo Gomina Amosun, bee lawon kan faramo Dapo Abiodun, tawon kan faramo Oloye Olusegun Osoba, tawon yooku si da duro.

Ojoojumo ni wahala olokan-o-jokan n farahan ninu egbe naa, to si mu ki Gomina AMosun maa leri nita gbangba pe oun setan lati ba enikeni to ba fe e ba oun du ipo naa lodun 2019 ja ija nla, nitori eni toun fa kale, iyen Adekunle Akinlade lo gbodo wole gege bi Gomina lodun 2019.

Kii se iroyin tuntun mo pe ore timo-timo ni Dapo Abiodun ati Akinlade, sugbon aigbora eni ye lo wo aarin awon mejeeji, ti won fi bere sii gbena woju ara won, ko da ti Gomina Amosun tun fesun kan igbakeji Aare orileede yi, Ojogbon Yemi Osinbajo ati alaga egbe oselu APC lapapo, Adams Oshiomole pe awon gan an nigi woroko to n da egbe naa ru l'Ogun.

Nigba to n soro, Dapo Abiodun so pe oun setan lati tesiwaju gbogbo ise akanse ti Gomina Amosun se lapati, nitori naa, ko fowo wonu lati sagbateru oun ninu idibo to n bo lona naa.

Ninu ifimufinle t'AWIKONKO se la ti gbo pe Gomina Amosun si duro lori ileri e pe oun ko setan lati gbe ipo naa fenikeni ju Adekunle Akinlade to je eni aami ororo oun lodun 2019 lo, nitori naa, ki Dapo Abiodun loo wabi jokoo si.

PÍN-IN KÁÀKIRI