E WO OMOBINRIN TO FE E FI ORUKO ALAAFIN OYO LU OBA IWO NI JIBITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 4, 2018

E WO OMOBINRIN TO FE E FI ORUKO ALAAFIN OYO LU OBA IWO NI JIBITI

Iwadi ti fidi re mule bayii pe omobibi ilu Iwo lomobinrin ti won ni o fee lu Oluwo, Oba Adewale Akanbi ni jibiti.


AWIKONKO gbo pe kii se igba akooko niyen ti yoo maa puro gbowo ka, se lo si pe ara re ni okan lara awon omoobabinrin Alaafin tilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi nigba to de odo Oluwo laaro ojo fraide to koja lo lohun, iyen ojo kerindinlogbon osu to koja yi.

Nigba ti Oluwo pe Oba Adeyemi lorii foonu ni asiri tu pe kabiesi yii ko ran enikeni si Oluwo.

Amo sa, leyin iwadi ni won rii pe omobibi ilu Iwo lobinrin pupa to ti bora tan ohun. Oluwo si ti gbe igbese lori omobinrin naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI