ẸGBẸ OṢELU PDP NIPINLẸ EKITI RỌ FAYOṢE L'OYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 4, 2018

ẸGBẸ OṢELU PDP NIPINLẸ EKITI RỌ FAYOṢE L'OYE

...A ṣi wa pẹlu Fayoṣe, eeyan wa ṣi ni lọjọkọjọ - Sẹnetọ Olujimi

Egbe oselu PDP nipinle Ekiti ti kede sita pe awon ti yo gomina ana nipinle naa, Ogbeni Peter Ayodele Fayose to tun je omo egbe kan naa pelu won gege bi adari egbe awon alenuloro ninu egbe naa.


Nibi ipade awon agbaagba egbe oselu naa to waye lai pe yi niluu Ado-Ekiti ni won ti daba a pe ki won yo Ayodele Fayose gege bi olori won, tawon omo egbe naa si fowo sii lesekese pe ki aba naa di imuse.

AWIKONKO gbo pe yiyo ti won yo Fayose ko seyin ejo to n je lowo ni kootu, latari esun ikowoje ati sise owo ilu mokumoku, eyi ti ajo EFCC fi kan an.

Lesekese ti won ti kede yiyo ti  won yo Fayose naa ni won ti fi Seneto Senato Biodun Olujimi toun gbajumo daadaa nile Yoruba rọpo e pe koun gba ipo naa.

Nigba to n soro, adari tuntun naa, Seneto Olujimi so pe "A mo nnkan ti Fayose ti máa la koja lahamo EFCC to wa lati bii ọjọ meloo kan seyin ki won too fi sile, a si mo pe ko le rorun fun un lati maa yoju sibi ipade yii. Ko si iyapa ninu egbe wa. Wi pe won yan mi gẹgẹ bi adari, ko tun mo si e wahala n sele ninu egbe wa.

"Lojo to gbe ijoba sile lo ti wa lahamo EFCC, a si mo nnkan to máa la koja nibe. A maa sise papo pelu Fayoṣe ni. A kò fe ko je pe bo se tijoba sile naa ni yoo tun je opin asiko é legbe PDP nipinle Ekiti.

"Nitori naa, é je ki n fi da awon alatileyin wa loju wí pe ibi kan naa la wa pẹlu Gomina Fayose atawon agbaagba egbe yooku. A kò pin rara, a sì máa sise takuntakun lati ríi pe a gba ipo gomina pada nibi idibo ti yóò tún waye.

Lara awon to wa nibi ipade naa ni alaga egbe oselu PDP nipinle Ekiti, Gboyega Oguntuase; igbakeji gomina ana, Dokita Sikiru Lawal; gomina fidihe teleri, Olatunji Odeyemi; igbakeji olori ile igbimo asofin teleri, Segun Adewumi; alaga ana legbe naa, Oloye Bolu Olu-Ojo.

Awọn yooku ni; awon adije sipo gomina; awọn omo ile igbimo asoju-sofin teleri; awon alaga ijoba ibile teleri atawon oloye egbé naa teleri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI