EGIPITI TA A KO NII RI MO LODUN 2019 NI AMOSUN ATI KASAMU - OGUNDELE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 21, 2018

EGIPITI TA A KO NII RI MO LODUN 2019 NI AMOSUN ATI KASAMU - OGUNDELE

Alaga igun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinle Ogun, Onarebu Sikirulai Ogundele ti je ko di mimo fawon omo ipinle Ogun, paapaa awon omo orile-ede Naijiria pe Egipiti tawon ko nii ri mo ninu Egbe oselu naa lodun 2019 ni Seneto Buruji Kasamu to je adije sipo gomina legbe oselu kan naa, iyen PDP ati gomina Ibikunle Amosun.


Onarebu Ogundele lo soro yii ninu atejade to gbe sita fawon oniroyin lojo Monde ijeta, eyi ti alukoro ẹgbẹ naa, Alaaji Malik Ibitoye bu owo lu lo ti so pe nnkan to da oun loju gbangba ni pe ajo eleto idibo, INEC to ni pe e paaro oruko Kasamu gege bi adije sipo gomina nipinle Ogun si oruko Onarebu Oladipupo Adebutu to je eeyan ti won.

Ogundele so pe ko ye ko je pe eni to si n jejo lowo latari esun kokeeni ti won fi kan an tun si maa ronu lati so pe oun fe e jade du ipo gomina nipinle Ogun to je gege bi awokose fawon ipinle yooku.

O loun mo pe eromode lasan ni Kasamu n se, ati pe awada to jinna sí otito ponbele ni okunrin tawon eeyan ko foju rere wo naa n se.

Ninu oro e, o so pe bawon ni eni ti orileede Amerika n wa lati wa a dahun awon ibeere nipa esun egboogi oloro ti won fi kan an je gege bi adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, gbogbo nnkan to n lo yi ko yato si awada kerikeri ti ko ni pe e wa s'opin."

Bẹẹ lo tun so pe bawo ni Kasamu ti kopa nibi idibo abele to waye koja lo se maa wa a di adije, to si je pe awon igbimo amuseya egbe naa latilu Abuja ni won ti wa a mojuto eto idibo naa.

Ni ti gomina Ibikunle Amosun, Ogundele so pe ẹgbẹ wọn ti ṣetan lati gba ijoba lowo ẹgbẹ oṣelu APC ti won dori gbogbo nnkan kodo nipinle Ogun, ti won tun ti ba gbogbo amusoro ipinle naa je.

Ninu oro e, "Ijoba Gomina Amosun ti ka awọn omo ipinle Ogun kule, oro e sí ti su awon araalu pelu bi ko se ni afojusun gidi fún won.

"Awọn omo ipinle Ogun gbodo mo pe owo won ni ojoola won wa, won sì gbodo ṣetan lati gba ara wọn sile lowo Farao (Pharaoh) yi to fe ki won sì maa gbe ninu iya Egipiti dipo ki won tẹsiwaju lo sile Kanaani (Cananland). Ati pe Egipiti ti a ri lonii, a ko nii ri won mo lati ọdún 2019 lo."

PÍN-IN KÁÀKIRI