PETER FIPA BA OMO E, OMODUN MEJI SUN L'EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 21, 2018

PETER FIPA BA OMO E, OMODUN MEJI SUN L'EKO

Tesan olopaa ni okunrin kan ti won pe oruko e ni Peter Adida wa bayii, to n gbategun, to si tun n salaye ohun to mo nipa bo se fipa ba omo e, omo odun meji sun, titi to fi fun un ni aisan ko gboogun.


Ojule kesan an, adugbo Oyetayo Olafisoye  ni Badore, lagbegbe Westwood Estate niluu Ajah ni won so pe okunrin naa n gbe.

Gege ba a se gbo, Ojo Abameta Satide to koja yii lowo awon olopaa ti te e, ti won si ti mu un si tesan won niluu Langbasa lagbegbe naa.

Ninu oro oga agba ni tesan olopaa ohun, Arabinrin Ada Okafor (SP) lo ti so pe, “Iwadii wa fi han wi pe nise ni okunrin yii ba omo e, omo odun meji sun titi to fi ko aisan buruku ran an.”


Ninu oro alukoro fun ileese olopaa, Chike Oti, (CSP) ni tie lo ti so pe “Nigba ti okan lara awon olopaa ti won je obinrin beere lowo omo naa wi pe ta lo ba se iru ere buruku bee, nise lo nawo si baba e, to si tun juwe orisirisi ara mi-in ti okunrin naa fi da lasiko to n fipa ba a lopo.”

O ni komisanna olopaa, Imohimi Edgal ti pase wi pe ki won gbe igbese iwadii gidi lori oro ohun, bakan naa lo ti wa ro awon obi ati alagbato lati maa mojuto awon omo won daadaa, nitori pe pupo ninu awon irufe onise ibi ohun ni won gba igboro kan bayii.

LATI: MAGASINNI ALORE

PÍN-IN KÁÀKIRI