EYI NI BI FEMI ADEBAYO SE BO LOWO AWON ADIGUNJALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 10, 2018

EYI NI BI FEMI ADEBAYO SE BO LOWO AWON ADIGUNJALE

Lojo Tosde to koja yii nisele ohun waye nigboro Eko, iyen lagbegbe 7up lojuna CMD, nitosi Ketu, l’Ekoo. Awon adigunjale kan ni won kolu moto Femi Adebayo, gbajumo osere tiata, ki oloju si too se e, won ti fa ibon nla yo, n loro ba di bo o lo o yago.


Ibon nla meji ti oruko e n je AK 47 ni won so pe awon ole yii ko lowo, ninu moto ayokele kan ti oruko e n je Toyota Corrolla ni won ti bo sile, lojiji ni won wa moto ohun di moto Femi Adebayo lona, nni won ba na ibon si moto omo Oga Bello, nni wahala nla ba de.

AWIKONKO gbo pe, gbogbo bi won se gbiyanju lati si oko ayokele yii ni ko see se fun won, bi won se bere si fi idi ibon jan moto naa niyen, ti won si ba gbogbo ara e je, pelu okan lara gilaasi moto ohun.

Ninu oro Femi Adebayo leyin isele ohun lo so pe: “Mo dupe lowo Olorun lori aabo e lori mi. Gege bi osere ati oloselu, eyi to mu mi maa wa lori irin lopo igba, bee to tun mu opo ewu lowo, sugbon a dupe lowo Olorun lori aabo e lori mi. Loni-in, ojo Tosde, ojo kejo osu kokanla yii, Olorun lo ko mi yo lasiko ti dereba mi koja lagbegbe CMD, ni Magodo to mori le ona Ojota, nise lawon adigunjale kolu moto mi, ninu moto Toyota Corolla kan ni won ti bo sile.

“Eeyan meji lo bo sile ninu moto ohun pelu ibon AK47 lowo. Nise ni won fe fipa si ilekun moto yen, nigba ti iyen ko see se fun won ni won ba bere si fi ibon lu gbogbo ara moto. Nibi ti won ti n se iyen ni won ti ba ilekun moto je, ti won tun ba gbogbo ara oko ohun je.

“Ohun to ba ni lokan je lori isele yii ni pe, gbogbo bi won se n se yii, awon eeyan wa nibe o, kaluku kan n ba tie lo ni, ti ko seni kan bayii to le se kai si won.  Awon eeyan ti mo n so yii, won ki i se olopaa, nitori won ko woso olopaa, bee ni ko si ami eyo kan bayii lara won to fi won han gege bi agbofinro. Losan gangan nisele yii waye o, ohun aburu gbaa ni.

“Mo mo wi pe ohun ti won lero ni pe, boya mo wa ninu moto yen, sugbon dereba mi nikan lo wa ninu e, emi wa ni lokesan nibi ti mo ti n sise lowo. Ope ni fun Olorun ti o je ko tete sare gbe moto yen kuro nibe, ope ni mo da lowo Olorun ti ko je ki dereba ba isele naa lo. Titi di asiko yii loro ohun si n se wa ni kayeefi, bee lara mi ko ti i bale pelu. Sugbon ju gbogbo e lo, a dupe wi pe ko si emi eni to bo sonu ninu isele buruku yii.

PÍN-IN KÁÀKIRI