GOMINA AREGBESOLA TI SO OPO AWON ALAINI DI OLORIIRE L"OSUN - ALAGBADA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 6, 2018

GOMINA AREGBESOLA TI SO OPO AWON ALAINI DI OLORIIRE L"OSUN - ALAGBADA

SEGUN OKEOWO

Komisanna fun oro okoowo, ileese ati alajeseku nipinle Osun, Ogbeni Ismail Adekunle Jayeoba Alagbada ti so pe isejoba Gomina Aregbesola ti fi iyun lelẹ lori oro okoowo nipinle naa, eleyii ti yoo si je manigbagbe laelae ati awokose fun awon ijoba to n bo.


Lasiko to n so nipa awon ise ribiribiri tijoba ti se lati le mu iṣẹ ati oṣi tan laarin ọdun mẹjọ to lo, Alagbada ni ko si olokoowo, yala, nla-nla tabi kekeeke to le gbagbe gomina Aregbesola nitori lasiko re ni iṣẹ wọn to ti denukọlẹ tẹlẹ gba isọji.

Alagbada ni oniruuru ona nijoba Aregbesola gba lati so awon araalu doloriire nipase ise agbe, eto ilera, idasesile ati eto aabo, eyi to fi awon araalu lokan bale lati sowo-jere, ti won si n na owo naa fun idagbasoke ipinlẹ Osun laiberu.

O fi kun oro re pe lati odun 2014 ti Gomina Aregbesola ti sagbekale ajo ayanilowo-sowo, iyen Osun Micro-credit Agency, ni igbe aye ọtun ti de ba awon olokooko kekeke; won lanfaani si eyawo ti ko gunpa, bee ni awon odo n ri ise se kaakiri nipinle Osun.

Alagbada ni bi ajọ kan ṣe so laipe yii pe ipinle Osun ni iye awon talaka re kere ju ko seyin afojusun tisejoba Gomina Aregbesola ni lati so gbogbo awon araalu to setan lati sise di eeyan pataki lawujo, ti won si gbe oniruuru eto kale fun imuse afojusun naa.

Gege bo se wi, biliionu meji naira ni ijọba gba latodo ileefowopamo apapo, CBN, eleyii ti won pin fun awon olokoowo kekeeke atawon alabọde fun idagbasoke ise won lai ni ele kankan lori rara, yato si milioonu lona ogorun naira ti won ti koko pin fun won, ijoba lo si n san ele ori owo naa pada fun ileefowopamo naa.

O ni ileese olokoowo kekeke ati alabọde ti won janfaani eto eyawo ti ko ni ele lori naa to egberun lona mejidinlogbon kaakiri ipinle Osun, bee ni awon araalu ti won to egberun lona metadinlaaadota ni won janfaani eto ikọsẹ ati ibaniwase ti ileese kan ti won n pe ni Grooming Center samojuto re.

Awon odo ti won din die ni irinwo nijoba tun ran lowo labe eto O'Yes lati bere ise agbe ogbin koko jijẹ (cocoyam) eleyii ti awon tijoba gba lati maa fun awon omoleewe alakobere lounje n lo labe eto O'mea, bee ni gbogbo awon ti won janfaani naa ko le gbagbe ijoba Aregbesola laelae.

Jayeoba Alagbada wa gbosuba fun ogbon inu ti Gomina Aregbesola fi tukọ ipinlẹ Oṣun fun ọdun mẹjo ti eto okoowo fi di apewaawo, ti ohun gbogbo si ru gọgọ si i yatọ si bi gbogbo nnkan se denukole ko too di pe o gun ori aleefa.

PÍN-IN KÁÀKIRI