O TAN O: AWON OSISE TI PADA SENU ISE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 6, 2018

O TAN O: AWON OSISE TI PADA SENU ISE


Apapo egbe awon osise lorileede Naijiria, NLC ti fagile iyanselodi to ye ko bere lowuro yii.

Te o ba gbagbe, koko ohun ti ijoba atawon egbe osise n fa mora won lowo ko ju ekunwo owo osu awon osise ti awon osise n beere fun.

Egbe osise lawon fe maa gba egberun lona ogbon naira losoosu (N30,000) gege bi owo osu osise to kere ju, nigba ti ijoba so pe oun ko le san ju egberun lona mejilelogun naira ati eedegbeta naira (N22,500) lo.

Ohun to fa wahala ree, eyi to mu egbe osise kede ki iyanselodi bere lowuro oni, ojo Tusde, Isegun, sugbon leyin opo wakati ti egbe naa ati ijoba apapo fi sepade, won ti kede wi pe ki awon eeyan awon si gbagbe iyanselodi ohun na.

Ekunrere bi won se pada yannju oro ohun la o maa fi to yin leti to ba ya

Lati: Magasinni Alore

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI