HAAA! MÁGÙN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 3, 2018

HAAA! MÁGÙN

Bùọdá alasuọta
Tí ń pín kárí ilé
Omi lọgbọ lọgbọ itan
Omi tútù, omi idẹra
Ọlọfa oro
Tí ń tà sì t'Arugbo t'Omidan lára.


Alabẹ ṣekele
Tí ń kọ pele ko abaja
Onkowe onigege ara
Onise alakada
Tí ń kotan àtàtà sórí iyamopo.

Bi o s'agbede
Kò sọmọ ajiroko
Ọ̀rẹ mi alagbede ọfa
Tí ń wá ewiri
Nínú agogo ìdẹ
Omuwe tó lè wẹ t'okun t'osa
Laarin ìṣẹ́jú aaya.

A rí pá ń t'ogun
Ọmọ ọdẹ
Tí ń p'odun oya, Pa àgbọ̀nrín
Nínú igbó dúdú abara tai tai
Igbo mo wo, mo wo
Igbo mo dé, mo de
Ojú ọ̀nà tóóró
Tio gb'ese méjì leekan.

Ajagun segun
Máa segun ota
Máa rẹyìn odi
Atepa, atekanle gbìn gbìn gbìn.

Baba yín l'ajiroko
Tí ń yẹko ọ̀nà
T'oun t'abẹ fẹlẹ
Tí ń kọ yẹri bí monamona.

Aponmi ta
Tí ń pọn sínú ládùúgbò gbogbo ilu
At'amu, at'igba, at'akeregbe
Gbogbo ẹ lomi tí kún bamu bamu
Ilé onílé tí rìn gbin gbin gbin.

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí m'omi amuju
Abẹnu tí wá ń kan yin
Jawe jawe yín
Tí jawe werepe ṣe kan-in kan-in
Le wa ń jíjó panduku láàárín igboro
Ẹ d'okoto tí ń t'akiti
Orí ilẹ̀ rainrain
Àkùkọ gagara
Tí ń kọ láàárín oganjo òru.

Lati Owo: Aremo Jah

PÍN-IN KÁÀKIRI