DAVID MU OTI YO, LO BA FIPA BA IYA É ATI IYA-IYAWO E SUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 3, 2018

DAVID MU OTI YO, LO BA FIPA BA IYA É ATI IYA-IYAWO E SUN

Kani kii se pe awon ara adugbo Muhata niluu Kaduna ko sun asunpara ni, o ṣee ṣe kí baálé ilé eni odun mejilelogbon kan, David Shakari tun na papa bora bo se se lodun to koja leyin fipa ba iya iyawo é sun tan.


Gege ba a se gbo, losu kejo odun to koja ni David lo sí odun ibile kan ti won se níjóba ibile Kaura, nibi ti iya e n gbé, ibe la gbo pe o ti mu ọti yo bamu. Bo se mu oti naa yo tan, lo ba gba ile ti mama é n gbé lọ.

Bo se dé bè, ibi ti mama é sun sí lo ti ba a, ko sí èrò meji ti won lòó wa síi lokan bi ko se Ibalopọ lo, lesekese lo ti fa sokoto é wa sile, to sì ṣe bẹẹ fipa wonu soobu mama é to ti le logota odun.

Nigba ti mama naa bere síi sunkun pariwo sita, to sì pé asiri é fe é tu, lo ba bere síi bẹ mama é. Aaro ojo keji ojo naa leyin ti oju é da tan, to rántí nnkan to se, lo dobale bebe pe oun ko nii se iru é mo.

Bo tile je pe mama naa dariji, to sì ṣe ọrọ naa ni oku oru, sugbon awon to gbo nnkan tó ṣẹlẹ ko soro naa sita, aarin ara wọn ni won ti n sọ ọ.

Lose to koja yi la gbo pe David tun lo sibi ayeye odun ibile kan to wa ladugbo ti iya-iyawo to n fe tẹlé n gbé, nigba tiwon máa ṣetan nibe, o ti mu ọti yo.

Ọti to mu yó naa lo je ko gba ile iya iyawo é lo, ibi ti mama naa sun sí lo ti ba a, to sì tún ṣe bẹẹ fipa ba iya toun naa ti laadota odun naa lasepo.

Igbe ti mama yi n ke lo ta s'awọn èèyàn leti, bi won se wole ni won ba a nibi to ti n ko ibasun fún mama naa, ki wọn too bere síi lùu. Ibi ti wọn ti fi lilu ba ti é je lo ti yó mo won lowo, to sì fẹ máa salo sugbon ti won tun pada ríi mu.

Ibe ni won gba gbe é dé tesan olopaa, to sì bẹrẹ síi bebe pe ki won se oun jeje, airikan-sekan lo je koun máa mú ọti kaakiri igboro. Àwọn èèyàn tó wà níbè ni won je kó ye awon olopaa pe iru nnkan to se yi lo se fún mama é lodun to koja.

PÍN-IN KÁÀKIRI