IFIPABANILOPO: AARUN TO GBODE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 24, 2018

IFIPABANILOPO: AARUN TO GBODE

Aye n lo, a n to o. Igba lo kuku ni ile aye, bee igba kan ko lo bi orere, aye na ko si gun bi opa ibon. Se awon agba bo nile Yoruba, won ni: Ogbon odun yii, omugo ni lodun to n bo. 


Bi aye ba ti n yi, ni kamaa ba won yi. Nitori ki aye ma baa yo ni sile laimo. Amo bi aye ba wa koju sodi, se dandan ni ka ba won yiju si oko iparun ni? Bi omo eda ba wa so iwa ibaje di iyekan, se dandan ni ka ba won tan? Awon iwaje ibaje ti n koni ni irira tele teleri ti wa fe e di ohun asegbayi lawujo bayii. Iwa egbin nigba kan ti wa di iwa gbajumo.

Iwa buruku gbaa lo je nigba aye awon baba nla wa bi okunrin eyikeyi ba gbiyanju lati fi tipa tikuuku je dundun obinrin eyikeyi. I ba je omidan tabi adelebo. Eni to ti balaga tabi eyi ti ko tii se bee. Amo sa, lasiko yi, iwa ohun ti wa a di toro fonkale. O ti di meji eepin-ni. O ti wa a di ajakale aarun lawujo wa.

O fere e je pe ojo kan ko ni i lo ki iroyin maa jade nipa bi enikan se fi ipa ba elomiiran lo po. Paapaa awon ogoweere tabi omode. Ohun buruku gbaa ni ka maa gbo pe baba olodun metalelaadota (53) fi tipatipa fi eyin omodun mefa-meje lele. A ti pe oro ohun lowe. O ti wa fe maa laro ninu. Alaborun ti wa fe di ewu si wa lorun ni gbagede.

Bi a ko ba tete wa egbo dekun si oro to wa nile yi, afaimo ki ogbara ojo re ma gba ile moni lowo. O ti wa di pe sasa ni odo to le fi owo soya pe ogidi ni oun. Se bi eni to pa ara re mo laise isekuse naa ni won ti n fagidi fo kuulu omi won yii.  Se bao ti wa maa ba lo ni yii? Ki lona abayo lati dekun iwa ibaje yii?

Die lowo omo olodun meta to ko tio rin, pupo lowo awon obi re.  O fere je pe ba ba ni ka da a sile, ka tun sa. Gbogbo wa la jebi esun yii.  Amo oniruru ona lo wa lati dekun iwa itiju to fe di ohun eye mo wa lowo yii.

Ona akoko ni pe kawon obi se ise won gege bi obi. Ki won ko awon omo won obirin bi won ti n mura lona to ye omoluabi.  Aso iwokuwo to gbode o je ka mo iyato laarin eni ti n sise asewo ati eni ti ko sise naa.  O ye ki awon obi ko awon omo won obirin lati mura lona ti yoo buyi kun ewa won lai ni si ara sile tabi eyi ti yoo mu ki igbonara dide lara eya odikeji.

Ona keji ni ki awon obi tun da awon omo won okunrin leko nipa bo ti ye ki won maa ko ara won nijanu.  Ti pe obirin kan wo aso iwokuwo o ni ki iru eni bee di eni ti ao te eto re mole tabi huwa ibaje si. O ye ki gbogbo okunrin mo ba ti n dari ara re. Ojuse obi ni lati se idaleko to jiire fawon omo won okunrin ki won le kapa agbara oofa ibalopo pelu enikeni lona aito.

Ona keta ni ki ijoba se ofin gbogi ti yoo se idajo enikeni to ba da aso irufe iwa bee se oro. Ilu tio sofin lese o si nibe. Bi ofin ba ti wa, dandan ni ki ese o wa. Bi ofin ba wa ti idajo ododo si n waye nibamu pelu ofin naa. Eyi yoo se adinku si iwa ibaje. Niwon bi kaluku yoo ti mo iya ti n be leyin hihu iru iwa bee. 

Bi awon aba meteeta yii ba le je nilo, adinkun yoo de ifipabanilopo lawujo wa. Awon ona meteeta yii oogun ajebidan si aarun ko gbogun to yo wole si aarin wa.

©Aremo jah

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI