IYAWO BABA SALA NAA TI KU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 2, 2018

IYAWO BABA SALA NAA TI KU O

Bi ipalemo se n lo, ti awon ebi n sapade lorisirisi lori bi eto isinku Baba Sala, Oloogbe Moses Adejumo yoo se waye laipe yii, okan ninu iyawo okunrin alawada naa tun ti ku o.


Falake Z. Adejumo, eni tawon eeyan tun mo si Emily Onikaba loruko iya to sese ku yii, eni odun metadinlogorin (77) ni, ki olojo too pe e sodo.

Okan lara iyawo Baba Sala ni mama yii, bee lo tun je ojulowo osere leyin oko e.

O fe ma si ere ori itage tabi sinima mi-in ti Baba Sala se nigba aye e, ti oruko Emily Onikaba ko ni i han ketekete ninu e.

Ojo Wesde ijeta, iyen ojo kokanlelogbon osu kewaa odun yii ni Oloogbe Falake Z. Adejumo jade laye, gege bi atejade ti okan lara awon omo oloogbe naa fi sori afefe, bakan naa ni eto isinku e ti bere lojo kin-in-ni osu kokanla odun yii.

Isin asale onigbagbo ni won yoo se fun un nile e ni ojule kokandinlogun, adugbo Obasekonla, Oke Ogun, niluu Owo nipinle Ondo.

Aago merin irole ni won so pe ero ohun yoo bere, nigba ti won si sin in lonii Fraide ojo keji osu kokanla.

Awon ebi ti so pe laipe yii lawon yoo maa kede eto ayeye isinku naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI