O KU DEDE KI DE-MOON KEKOO GBOYE NI WON PA A DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 3, 2018

O KU DEDE KI DE-MOON KEKOO GBOYE NI WON PA A DANU

Iroyin ti ko fi béè  dun mo èèyàn ninu niroyin  to te AWÍKONKO lowo láì pe yi nipa bawon omo egbe okunkun se yinbon pa odomokunrin tojo ori e ko tii ju odun metadinlogbon, ta a gbo pe odun yi ni yóò kẹkọọ yege níleeko gbogbonise.


Bo tile je pe a ko tíì moruko é titi dasiko ta a ko iroyin yi tan, sugbon ta a gbo pe De-Moon lopo awon èèyàn món on síi, akékòó ileeko giga gbogbonise ijoba apapo nipinle Anambra, iyen Federal Polytechnic Okon.

Ale ojo Tosde ijeta nisele naa ṣẹlẹ, bawon kan se n so pe awon omo ẹgbẹ okunkun ni won n ba ara won fa wahala ko too di  pe De-Moon, ti eka ikekoo eto ile-ifowopamo ati ìṣúná (Banking and Finance) lòó yoju sibe, to sì ṣe bẹẹ fara gbóta.


Bẹẹ láwọn kan n so pe awon adigunjale ni won wa sọsẹ́ lale ojo naa ko too di pe De-Moon gbe foonu é lati ya foto, lara adigunjale naa ti won loo ri ni won loo sunmon lati gba foonu  naa lowo e, toun ko si mo, ibi tá a gbo pe won ti n fa oro naa ni won ti yinbon fún, ko too di pe won gbe okada salo pelu foonu é.

Ìró ìbon to dun naa lo ko ibẹrubojo bawon akekoo to wa layika naa, paapaa olugbe àwọn ará agbegbe yi. Nigba ti won sì máa debi isele naa, oku De-Moon ni won ba ninu agbara eje.

PÍN-IN KÁÀKIRI