WON LE OKEY LENU ISE SOJA, LO BA FIPA FA IDI OMODUN META YA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 2, 2018

WON LE OKEY LENU ISE SOJA, LO BA FIPA FA IDI OMODUN META YA

Bo tile je pe a ko tii le fìdí è mule boya owo olopaa ti te Okey Nna L'ogbon ti won fesun kan pe o fipa já ibalẹ Favour, omodun meta lojo Tusde to koja yi, sugbon ohun tá a gbo ni pe gbogbo ọnà ni Okey n wa lati pa omodun meta naa ati iya é, Ruth Ani danu latari bo se tu asiri é sita.


AWÍKONKO gbo pe ni nnkan bi aago mẹjọ aabo ale ojo Tusde naa ni Okey ti won ni won sese lẹ danu lenu Ise soja latari awon esun odaran ti won fi kan an lòó fipa ki omodun meta naa mole nile akoku toun ati mama n gbé, to sí fipa ba a sun.

Agbegbe Mpape nitosi Asokoro niluu Abuja nisele naa ti waye. Àdúgbo kan naa la sí gbo pe Favour ati iya é, Ruth pẹlu Okey n gbe.

Ariwo ẹkun Favour lo kan sí mama é, Ruth Ani nibi to wa, to sí sáré lòó yoju síi, nigba tí yóò fi de'bẹ, Okey lo ba lori ọmọ e, to n ko ibasun fún karakara.


Bi Okey se ríi pé asiri oun ti tu si Ruth lowo, paapaa nigba tiyen bo ọ mọlẹ nibi to ti n ba omo é sun, lo ba bèrè síí luu, to ku die ko pa a, sugbon to raaye sà món on lowo.

Latigba naa la gbo pe Okey ti won lòó gbajumo dáadáa ladugbo náà, paapaa gege bi Soja ti won sese le kuro lenu ise ti bere síi dunkooko mo Ruth pe to ba gbe oro naa sita, se loun yóò pa a danu bi adiẹ.

Aaro ojo keji, iyen Wesde nigba ti eje bere síi da koja afenuso lábé ọmọ e, lo ba lòó koju Okey fúnra è pe se ni ko kuku pa oun, sugbon ti won ni Okey tun fi lulu ba ti é je, igba to ku die ko pa a, lo ba salo fún un.

Latigba yi la gbo pe Ruth ti mu ọmọ e sa kuro lagbegbe naa, tá a ko sí tii le so ibi to wa titi dasiko yi. Bẹẹ láwọn araalu n rawọ ebe s'awọn olopaa lati sise won bíi iṣẹ, ki wọn sì fi Okey sahamo won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI