EMI KI YOO KU IKU-KIKU KAN, BI KO SE YIYE - BUHARI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 3, 2018

EMI KI YOO KU IKU-KIKU KAN, BI KO SE YIYE - BUHARI


Lorile-ede Poland lohun-un ni Aare Muhammed Buhari ti fun awon alatako e lesi awuyewuye to gba igboro kan wi pe, baba naa ti ku, ati pe oun gan-an ko lo n dari akoso orile-ede yii.

Lodun 2017 ni oro yii bere were, nigba ti Nnamdi Kanu, eni ti se olori awon IPOB, iyen egbe to n ja fun bi awon eya Igbo yoo se ya kuro lorile-ede Nigeria.

Ohun ti okunrin omo Ibo yii ko sita ni pe, ki i se Buhari tawon eeyan dibo yan lodun 2015 lo wa nipo Aare Nigeria. O ni, o pe ti Aare Buhari ti ku, iyen lasiko igba to lo gba itoju lori-ede Geesi lohun-un.

Bakan naa lo fi kun un pe, okunrin kan ti oruko e n je Jubril lati orile-ede Sudan gan-an ni won fi ropo Buhari leyin ti baba naa jade laye.

Were ti oro ohun bere niyen o, bee ni Femi Fani Kayode naa tewo gba a, ti oun naa si gba ori agbon kan lo, lori ero ayara-bii-asa, iyen twitter handle e, nibi to ti ko o jade wi pe o digba ti Buhari ba fipo sile, ki oye e too ye awon eeyan wa wi pe ki i se Ogagun Muhammed Buhari tawon omo Nigeria dibo yan lo n dari akoso orile-ede yii. 

O ni, iyalenu nla lo maa je fun opolopo eeyan nigba to ba sele.

Sa o, Aare Muhammed Buhari ti bu enu ate lu gbogbo awon eeyan to n gbe irufe iroyin yii kiri. 

O ti so pe, “Emi Muhammed Buhari te e fun lase lati di aare orile-ede Nigeria lodun 2015 naa lo dari yin o, emi ko ku o, bee ni won ko fi enikeni ropo mi. Awon to n gbe irufe iroyin bee kiri, awon eeyan ti won ro pe mo ti ku lasiko igba ti mo lo gba itoju ni, bee riro ni teniyan, emi ko ku rara.”

Aare Buhari ti wa fi da awon eeyan loju, paapaa awon omo orile-ede yii ti won wa ni Poland, to se ipade pelu won, wi pe, oun ti won dibo yan lodun 2015 naa niyi, ati pe laipe yii gan-an loun yoo sayeye ojoobi oun, nigba ti oun ba pe eni odun merindinlogorin (76).

Bakan naa ni Aare so pe, ohun ti awon eeyan n gbe kiri wi pe oun ti ku yii, ohun iyalenu lo n je fun igbakeji oun, Ojogbon Yemi Osibajo, nitori opolopo awn eeyan yii ni won n be Osibajo bayii wi pe ko fi awon se igbakeji aare, eyi to n se tohun ni kayeefi gidi.

Lati: Magasinni Alore

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI