EGBE OSELU APM KO LE DIBO FUN IBIKUNLE AMOSUN GEGE BI SENETO LODUN 2019 - MUSEFIU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 3, 2018

EGBE OSELU APM KO LE DIBO FUN IBIKUNLE AMOSUN GEGE BI SENETO LODUN 2019 - MUSEFIU


Egbẹ oṣelu Allied Peoples' Movement, APM nipinle Ogun ti fidi e mule pe ko sí nnkan to kan won kan ẹgbẹ oṣelu APC, paapaa idibo Seneto to kan gomina Ibikunle Amosun lodun 2019.

Onarebu Lamidi Musefiu Olatunji, to ti figba kan ri je alaga ijoba ibile Ado-Odo Ota, to tun gbenuso fun ẹgbẹ oṣelu naa lo soro yi nibi ipade toun atawon adije merindinlogbon sipo omo ile igbimo asofin ipinle Ogun lodun to n bo se pelu awon oniroyin ninu gbongan alejo ti Presidential Lodge.Olatunji so pe bo tile je pe awọn ti kuro ninu ẹgbẹ oselu APC, sibe iyen ko so pe kawon ma dibo fun Aare Muhammadu Buhari, ati pe nitori é láwọn ko se fa adije sipo Aare kale ninu ẹgbẹ naa.

Nigba to n soro lori idi ti won se fegbe naa sile, Agbenuso naa so pe nigba tawon rii pe naa awon alagbara ninu ẹgbẹ naa fe e fowo ola gba won loju lo je kawon pinu lati fegbe naa sile lo sibomin in.


Bee lo tun so pe gbogbo ona láwọn yóò gba lati ríi pe adije sipo gomina labẹ egbe oselu naa, Onarebu Abdulkabir Akinlade wole gege bi gomina lodun 2019, nitori tawon ti gbaradi fún idibo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI