KERESIMESI: OGA AGBA VGN NIPINLE OGUN SELERI ETO AABO TO PEYE FAWON ARAALU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 14, 2018

KERESIMESI: OGA AGBA VGN NIPINLE OGUN SELERI ETO AABO TO PEYE FAWON ARAALU

Bi a ba n so nipa ileese eleto aabo to sunmo awon araalu daadaa, odu lawon Fijilante, paapaa awon VGN tijoba apapo, won kii sai mo foloko, opo awon araalu ni won si ti n kan saara si won ni gbogbo igba pelu awon akanse ise lati daabo bo emi ati dukia awon araalu.

Bawon ileese nla-nla ati kereje-kereje se n gbosuba kare fun won, bee lawon iyaloja, awon agbaagbe lawon agbegbe kaakiri naa n gbe osuba kare fun won, paapaa bi won tun se n fowosowopo pelu won nipa idanilekoo ati oniruuru eto to nii se pelu oro eto aabo.

Lai pe yi ni adari egbe Fijilante, VGN, Komanda Nureni Olanrewaju Adedoyin ba Olootu Iwe Iroyin AWIKONKO, SEGUN OKEOWO soro nipa awon aseyori won laarin osu kinni odun yi, si osu ta a wa yi, paapaa nipa eto ti won ni fawon araalu, bi asiko odun keresimesi se n sunmo etile.

Olanrewaju so pe oniruuru eto olokan-o-jokan nileese won ti la kale lati rii pea abo emi ati dukia awon araalu daju, nitori pe nnkan to se Pataki ju sawon niyen, idi ni yii tawon fi fise adani tawon n se sile, tawon si loo bere ise naa.

O ni biru asiko odun bayii bat i n sunmo etile lawon onise ibi maa n kaakiri lati wa nnkan ti won maa jig be, ati bi won se maa femi eeyan sofo, ti won a tun pinu lati feeyan sofo nitori owo ojiji ti won n wa.

Komanda Olanrewaju ni ileese won, paapaa nipinle Ogun, awon ti gbe ise le gbogbo awon osise won lowo lati rii pe ko seni to huwa odaran laarin ilu atawon igberiko kaakiri ipinle. Bee lo to pe titi de awon ile ifowopamo atawon ibi ti won ti n gbowo pajawiri, ATM ni ki won maa sabojuto.

Ninu oro e, Olanrewaju so pe “A ni eto ati ilana ti wa ta a gbe kale fun ayeye odun to n bo lona yi, iyen odun keresimesi. A ti ran awon osise wa patapata lati loo daabo boa won eeyan ilu. A tun ti ran won loo darapo mo awon olopaa, FIB, ileese otelemuye, ajo eso oju popona atawon to n ri soro egboogi oloro, ati beebeelo. Won gbodo rii pe won fo ilu mo tonitoni.

“Nigba ti ilu ba wa nimototo, a maa rii pe ko ni siwa odaran, eeyan ko ni ronu lati huwa odaran, alaafia a si wa. Kaakiri awon igberiko, agbegbe la ti yan awon osise wa lati loo sise aabo. Ko si iberu fawon araalu nitori pe digbi ni eto aabo ta a ti se sile.”

Nigba to n soro nipa ipo ti eto aabo wa nipinle Ogun, Komanda naa so pe ipo to dara ni eto aabo wa, sugbon nnkan to kan fe e je ko maa mehe diedie ni toro oselu to wa nita bayii, sugbon gbogbo e lo wa labe ikawo wa.

Nipa ti aseyori won laarin osu mejila seyin, o ni orisirisi aseyori tawon ko le ka tan nileese won ti se, tawon araalu, atawon ileese eleto aabo si ti gbe osuba kare fun won. Lara e si ni ti awon odaran ti won pa baale ile kan, ti won ge eya ara e si wewe, to je pe awon osise won ni won rowo to awon odaran naa.

Okunrin to mo nipa eto aabo daadaa naa tun je ko di mi mo pea won ti towo bowe adehun pelu ileewe fasiti Ahmadu Bello lati fun awon ti ko leto to yanranti lekoo to peye, bee lo tun lawon kowo bowe adehun papa pelu ileewe fasiti Southwestern.

Bo tile je pe ko sise to yanranti ti ni adojuko, nigba to n soro lori adojuko ileese won, Komanda Olanrewaju so pe opo adojuko lawon ni, sugbon eyi to lewaju gbogbo e ni ti isoro aisi irinse ati irinse, paapaa isoro owo ti ko to lo n fa tileese won fi n padanu awon ise kookan.

Fun idi eyi, oga agba naa ro ijoba apapo, ijoba ipinle ati ijoba ibile, to fi mo awon ileese adani lati dide iranlowo si won, ki ise won si le tubo yanranti daadaa.

Ni ti eto idibo to n bo lona ati ipolongo idibo to n lo lowo, Adedoyin ni awon ko si fun enikeni bi ko se gbogbo eeyan, ati pe awon ko si leyin oloselu kankan bi ko se pee ni to ba kowe iranlowo nipa eto aabo lawon yoo dide iranlowo si.

Lakotan, oga agba naa wa gbawon araalu atawon oloselu lamonran pe ki won yago fun nnkan to le mu ki won sewon, paapaa lasiko odun ati oselu to wa nita bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI