KERESIMESI: SOOSI TREASURE HOUSE OF GOD FE E FOUNJE BO EGBERUN MARUN EEYAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 16, 2018

KERESIMESI: SOOSI TREASURE HOUSE OF GOD FE E FOUNJE BO EGBERUN MARUN EEYAN


Gbogbo eto lo ti pari bayii nile ijosin ile isura ti Olorun iyen Treasure House of God, to wa lona Quarry, Abeokuta, nipinle Ogun, nibi ti won ti fee bo egberun marun un eeyan lojo odun keresi, lojo keedogbon osu yii, tii se ojo odun keresimesi.

Gege bi atejade ti Ogbeni Adeniyi Adeloye to je oluranlowo pataki fun eto iroyin fun oludasile ijo naa, Pasito Adeseye Senfuye fi sowo si AWIKONKO lo ti salaye pe gbogbo awon eeyan to ba wa sibi ayeye naa ni ireti wa fun un pe won yoo mu ebun lo sile.

Bee lo ni ko nii se pelu esin, ilu tabi oselu, gbogbo awon eeyan ti Olorun ba fun nu oore ofe ni didun losan yo so fun won lojo naa.

O salaye pe awon ko sese bere eto naa, o ti le lodun meloo kan seyin tawon maa n bo awon araalu, kawon naa le sodun pelu ayo ati idunnu.

O ni igbagbo oludasile ijo naa, Pasito Senfuye to fi sagbekale eto olodoodun naa ni wa laaye kawon eeyan naa si wa laaye pelu.O ni ohun ti akori todun yii dale lori ni Jesu bo awon eeyan. O ni Jesu leni akoko to bo awo eeyan, ipase e lawon naa si n tele.

Adeloye ni lodun to koja awon eeyan bii egberun merin lawon seto naa fun sugbon todun yii tun ti loo soke si egberun marun un.

O ni Diakoni Kayode Ogunjimi to je alaga igbimo eto naa ti mura sile pelu awon eeyan e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI