O MA SE O: SINA LU IYAWO E PA L'AGBADO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 19, 2018

O MA SE O: SINA LU IYAWO E PA L'AGBADO

Lasiko tawon eeyan n gbadura pe ki Olorun ma je kawon ko sinu wahala bi odun se n bo yi, ni baale ile eni odun mejidinlogoji (38) kan, Shina Kasali ki iyawo e, Sofiat Kasali mole, to si luu pa, iyen lojo kinni in osu yi, to si daju pe ogba ewon ni Shina yoo ti sodun.


Bo tile je pe oun ta a gbo ni pe obinrin naa, Sofiat la gbo pe o n fooro emi oko e nitori ti ko sise lowo e mo, eyi ti won lokunrin naa ti n gba mora latigba ti ko ti rise se mo.

AWIKONKO gbo pe ati nnkan bi osu meta si merin seyin ni Shina ti won nise alapata lo n se ko ti lo sibise mo, latari bi nnkan se dorikodo fun, latigba naa la gbo pe Sofiat ti n gbe bukata, sugbon won ni kaka ki Sofiat maa gba oko e lamonran, se lo tun n gbe emi e soke latari airise se e.

Ohun ta a tun gbo ni pe lojo tisele buruku naa waye, iwaju ita ile ti toko-taya naa n gbe ladugbo Abosule, Agbado nijoba ibile Ifo ni Shina jokoo si to n gbategun, ko si pe ti won niyawo e, Sofiat fi jade lati loo pon omi nile keji.

Won ni bi Sofiat se ri Shina nibi to jokoo si lo ti bere sii so awon oro abuku sii, ko da a, ti won loo tun fesun kan an pe se lo n ranju mo abe obinrin kan ti won nise asewo lo n se, eni ti won loo jokoo sookan ile won, to si tun n pe oko e ni asewo, olojukomuolo.

Awon eebu ti won ni Sofiat n bu Shina ni won loo bii ninu ti won si i lu ara won. A gbo pe awon araale ti won jo n gbe ko koko da si won lasiko naa nitori ti won ni ojoojumo lawon mejeeji maa lu ara won,ti won si loro won ti su awon araale.

Won ni pelu binu ni Shina fi n lu iyawo e lojo naa, ko too di pe o fori gbale, to si bere sii pofolo nile.

Ere la gbo pe won koko pe e, afigba ti won rii pe emi ti fe jabo lara e, ki won too sare sunmon on lati ran an lowo, nigba ti won gbe e soke ni won rii pe o ti fe e yiwo, idi ni yii ti won fi sare da omi le e lori.

Gbogbo akitiyan lati rii pe Sofiat ko gbabe ku ni won loo ja si pabo, eyi to mu ki won gbe e gbona osibitu lo, sugbon ti won ni oju ona lo ti dake.

Ariwo ikunle abiyamo ni won lawon araadugbo naa n pa nigba ti Sofiat ku, idi ni yii ti won ni okan lara awon araale toko-taya naa, Ogbeni Tunde Babatunde fi gba tesan olopaa lo lati loo fejo sun.

Gbara tawon olopaa ti gbo la gbo pe won ko ti f'oro naa fale rara, ti won fi gba ile naa lo lati mu Shina. Ohun ti won loo yawon olopaa lenu ni pe enu ekun ni won ba okunrin alapata naa nigba ti debe.

Nigba ti won n f'oro wa a lenu wo, baale ile naa so pe gbogbo akitiyan oun lati ni suuru lo n ja si pabo, pelu b'iyawo oun se maa n gbe oun lemi soke, o ni latigba ti nkan ti denukole foun ni Sofiat ti n gberaga soun, to si tun ma maa fiwosi lo oun.

O lopo igba lawon araale ti ba a soro, ti won tun maa n bawon pari ija, sugbon kaka ko ro lara iyawo oun, se ni wahala naa tun n po si.

O tun fi kun oro e pe lojo naa, ori ironu b'oun yoo se ri ona abayo paapaa lasiko ti odun n bo yi loun wa ti Sofiat fi wa a ba oun nibi toun jokoo si niwaju ita ile won, iyen bo se n koja lo lati loo pon'mi, to si bere sii fesun agbere kan oun, to tun n fi alebu ara bu oun.

Ibinu yi lo loun fi dide lati seru ba a, lai mo pe se lo maa gbe oro naa pari, ko pe tawon si bere ija lo subu lulè, to di pe awon araale wa a da omi le e lori. O nibi tawon ti n gbe e lo si osibitu lati doola emi e lo ti dake.

Komisanna olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu ti so pe ki eka ileese won to n ri soro odaran, iyen Homicide tesiwaju iwadii, bee lo ni ki oku Sofiat si wa ni mosuari osibitu jenera ti Ifo fún ayewo titi tawon yoo fi pari iwadii won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI